Ọmọ méjì kú, ọ̀pọ̀ dẹnukọlẹ̀ sínú ọkọ̀ iléẹ̀kọ́ l‘Eko, tori ooru àmújù

Aworan oko

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ileeṣ̣ẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ni lọọtọ ni iṣẹlẹ iku ọmọ meji to gbẹmi mi nitori ooru inu ọkọ waye nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin to fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba ni aibikita awakọ ileẹkọ, School Bus naa lo fa iṣẹlẹ ijamba naa.

Ileẹkọ Handmaids International Catholic School ni agbegbe Aguda, Surulere nipinle Eko ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn ọmọ meji to ku ninu awọn ọmọ to le ni ogun to wa ninu ọkọ naa ni Izuorah Sochima Victor ati Ilofunlunwa Ugomsinachi.

Awọn ọmọ mejeeji naa lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.

Aibikita awakọ naa lo ṣekupa awọn akẹkọ o - Ileesẹ Ọlọpaa

Ninu ọrọ rẹ, Agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa naa ni awọn n gbe awakọ ‘school bus’ naa lọ si ileẹjọ ti awọn ba ti pari gbogbo iwadii tan.

Hundeyin ni awakọ naa ko bikita nipa awọn ọmọ to gbe sinu ọkọ ni iṣẹlẹ buruku naa ṣe waye.

O fikun un pe awọn iwadii ti awọn yoo ṣe yoo ṣayẹwo iru iku to pa awọ̣n ọmọ naa.

Bakan naa lo ni ileewosan yoo sọ boya aisi atẹgun ninu ọkọ naa, abi awọn ọmọ naa n ṣe aisan tẹlẹ, ni wọn ṣe ku.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ileẹjọ ni yoo sọ boya ẹsun ipaniyan ni wọn fẹ fi kan awakọ naa abi ẹsun miran, to ba jẹbi rẹ.

Ojo to n rọ lo mu ki n ti ferese ọkọ mawọn akẹkọọ - Awakọ

Wayi o, awakọ mọto ileẹkọ naa ti wa salaye idi to se ti ferese mọ awọn ọmọ naa.

Awakọ ọkọ naa to ba akọroyin Vanguard sọrọ ni ojo rọ ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ti o si jẹ ki ọkọ oun wọnu ọpọlọpọ omi.

Lẹyin naa ni oun ti ferese ọkọ, ti oun si duro lati fẹ taya ọkọ oun.

Lẹyin naa ni oun wọle sinu ọkọ amọ ti awọn ọmọ naa n pariwo ti oun siro pe wọn n dapara ni amọ oun ko kọbi ara si wọn.

O ni igba ti awọn de ile ọkan ninu wọn, ti oun jade ninu ọkọ, loun n ri ti awọn kan ti dakẹ ninu awọn ọmọ naa, ti awọn miran si n bi eebi ninu ọkọ naa.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn gbe wọn lọ si ileewosan,ti wọn si fi Oxygen ji awọn kan ninu wọn, amọ ti awọn ọmọ meji ti papoda.

Oju mi ni Junior aburo mi, se sun lọ sinu ọkọ – Ẹgbọn oloogbe

Ọkan lara awọn akẹkọọ to jajaye ninu ọkọ naa ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ninu ọkọ naa, ki aburo rẹ to gbẹmi mi.

Ọmọbinrin to ba ileeṣẹ iroyin Vanguard sọrọ ni awakọ wọn ti wọn n pe ni ‘Uncle Mandella’ ni awọn kesi ati ṣi ferese ọkọ amọ ko da wọn lohun.

‘’Mo ni Uncle Mandella, aburo mi n sun amọ ko tilẹ da wa lohun, titi ti a fi de ile ọkan lara awọn ti a jọ wa ninu ọkọ.

‘’Amọ ki a to de ibẹ, aburo mi ti sun lọ.’’

Ọdun mẹ́fa ni mo fi duro ki n to ri ọmọ bi - Iya oloogbe

Bakan naa ni iya ọmọ keji to ku ninu iṣẹlẹ naa, Izuorah Sochima ti barajẹ wi pe lẹyin ọdun mẹfa ti oun ti n wa ọmọ ni oun ṣẹṣẹ ri eleyii to ṣalaisi naa bi.

O tun fi aidunnu rẹ han si bi ileẹkọ naa ko se kọbi ara si wọn lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye.

Amọ awọn alaṣẹ ileẹkọ naa ni awọn ṣabẹwo si awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si, amọ ọkan lara awọn mọlẹbi naa ṣekọlu si wọn.