Ademola Adeleke yan ìgbìmọ̀ tí yóò mójútó bí agbára yóò ṣe pàárọ̀ ọwọ́ ní Osun

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Instagram
Gomina tuntun ti wọn dibo yàn nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, tí yan igbimọ tẹ̀ẹ́kótó, ẹlẹni mẹtadinlogoji, ti yoo ṣe amojuto bi agbara yoo ṣe paarọ ọwọ laarin rẹ ati ijọba to wa nipo bayii.
Ikede nipa igbimọ naa jẹyọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ẹgbẹ́ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ naa, Oladele Bamiji, fi sita lọjọ Iṣẹgun.
Ọgbẹni Bamiji sọ pe àwọn onimọ ninu oríṣiríṣi iṣẹ́, awọn to di ipo oṣelu mú, ati awọn akọṣẹmọṣẹ lo wa ninu igbimọ naa.
Bakan naa lo sọ pe Ọjọbọ ni Adeleke yoo ṣe ifilọlẹ igbimọ naa ni gbangba.
Oludari eto ìpolongo ibo fun Ademola Adeleke, Aṣofin Sunday Bisi, ni yoo jẹ igbakeji alaga igbimọ.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ni Ademola Adeleke ti ẹgbẹ́ oṣelu PDP, fi ẹyin gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola janlẹ ninu idibo gomina to waye.
Ìjọba ibilẹ mẹtadinlogun ninu ọgbọn to wa nipinlẹ naa lo ti bori pẹlu apapọ ibo 403, 371.
Gomina Oyetola ti APC ní 375,027.












