Èmi ni màá kọ́kọ́ bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba rẹ tí o bá kọ̀ láti mú ìlérí rẹ ṣẹ - Baba Davido

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, @Adeleke

Dókítà Deji Adeleke tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún gómìnà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti sorosoke.

O ni pe òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò kọ́kọ́ bu ẹnu àtẹ́ lu àbúrò òun tó bá kọ̀ láti mú àwọn ìlérí tó ṣe ṣẹ. Dókítà Adeleke ní ó pọn dandan fún Adeleke láti ṣe àmúṣẹ gbogbo ìlérí tó ṣe fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun lásìkò ìpolongo ètò ìdìbò. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ gboyè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Adeleke tó wà ní ìlú Ede lo pàrọwà sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ olórí tàbí ọmọlẹ́yìn rere ní ààyè tí wọ́n bá ti bá ara wọn.

Ó ní kò yẹ kí àwọn olórí máa fi ipò wọn yan àwọn ọmọlẹ́yìn wọn jẹ nítorí ìgbà ò tọ́ lọ bí òréré. Bákan náà ló bú ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń ta àti ra ìbò lásìkò ètò ìdìbò. Ó ní ẹnikẹ́ni tó bá ti gba owó lọ́wọ́ olóṣèlú kó tó dìbò kò ní lè àǹfàní láti sọ̀rọ̀ tí ìjọba kò bá ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Ademola Adeleke náà báwọn péjú síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde náà níbi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní first class ti jẹ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.