Ekiti Ghost Workers: Gómìnà Fayemi ní N400m ló ń sọnù ní ọdọọdún nítorí àwọn tó ń gba owó òṣù láì ṣiṣẹ́

Ekiti

Oríṣun àwòrán, Google

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti sọ wi pe iye owo ti ipinlẹ Ekiti n sọnu ni ọdọọdun to irinwo miliọnu Naira nitori awọn to n ṣiṣẹ lai gba owo ni awọn ijọba ibilẹ.

Akọwe eto iroyin fun gomina Kayode Fayemi, Olayinka Oyebode lo fi lede bẹẹ ninu atẹjade kan.

Ninu atẹjade naa ti wọn pe akọle rẹ ni 'Ekiti Loses N19.3m Monthly To LG Ghost Workers - Report', ni Fayemi ti kọminu lori bi awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ wa ni ipinlẹ Eko ti wọn si n gba owo oṣu ni ipinlẹ Ekiti.

Gomina Fayemi ni o ṣeni laanu wi pe awọn to n gba owo oṣu yii ko le e sọ pato ohun ti wọn n fi owo oṣu naa ṣe.

Gomina naa fi ero rẹ han lẹyin ti o ri esi iwadii ti ijọba gbekalẹ lati ṣe ayẹwo awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa.

'' O kere tan eniyan mejilelọgọtalelelọọdunrun lo n gba owo oṣu lai ṣiṣẹ ni ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Ekiti.''

'' A ko gbọdọ dakẹ lori ọrọ yii mọ nitori awọn kan joko si Eko, wọn si n gba owo oṣu ni Ekiti lai nidi''

Bakan naa ni gomina Fayemi naa wa fikun wi pe awọn yoo fi ohun gbogbo sipo ti iru awọn iwa buruku yii ko ni waye mọ.