US presidential election 2020: Àwọn àkọ́lé ìròyìn tó leè jáde lẹ́yìn ìdìbò Ààrẹ Amẹrika

Trump gives thumbs up

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni bayii ti idibo sipo Aarẹ ilẹ Amẹrika ti bẹrẹ ni pẹrẹwu, ibeere ti ọpọ awọn eeyan atawọn onwoye ohun to n lọ n bere ni pe ta ni yoo gbegba oroke ninu idibo naa?

Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti n woye ibi ti esi idibo naa yoo fori sọ.

Ṣe Aarẹ Donald Trump ni yoo tun wọle fun saa keji ni tabi Joe Biden ni yoo yẹ aga mọ nidii?

Fun ẹnikẹni to ba wọle ninu Trump tabi Biden, iru akọle iroyin to lee jade ree:

1.Irọrun ni Joe Biden fi yẹ aga mọ Trump nidii

Ohun akọkọ to lee ṣẹlẹ ni ki Joe Biden jaweolubori pẹlu irọrun.

Lati igba ti ipolongo ibo ọhun ti bẹrẹ ni Joe Bide ti n tiraka lati bori ninu idibo naa.

Bi Biden ṣe n lakaka naa ni Aarẹ Donald Trump naa ṣe n gbiyanju lati wọle fun saa keji.

Queue to vote in Georgia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi awọn kan ṣe sọ, lara akitiyan Biden lati wọle ni bo ṣe yan obinrin to jẹ alawọm dudu gẹge bi igabkeji rẹ, iyẹn Kamala Harris.

2.Trump jaweolubori lọna to ya awọn eeyan lẹnu

Ohun keji to lee ṣẹlẹ ni ki Donald Trump bori lọna ti yoo ya awọn eeyan kan lẹnu.

Lara ohun to lee sọ bi aṣeyọri Trump yoo ṣe ri ni awọn esi ti yoo wa lati Pennsylvania ati Florida.

Iwadii kan fi han pe ogunlọgọ awọn oloufẹ Trump lo n gbe ni awọn ilu nla kan bii Florida, Ohio, Tennessee, Pennsylvania, North Carolina, Georgia ati Virginia.

Joe Biden takes off his sunglasses

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin ni awọn eeyan naa fẹran Trump to bẹ ti o fẹẹ jọ bi pe wọn lee fi ẹmi wọn lelẹ fun ọkunrin ọhun.

Idi miran ti awọn onwoye tun fi sọ pe o ṣeṣe ki Trumnp bori lọna ti yoo jọ awọn eeyan kan loju ni igbagbọ pe o mọ bi wọn ṣe n polongo ibo ju Biden lọ.

3.Biden gbo ewuro soju Trump

Ohun kẹta ti awọn onimọ nipa eto oṣelu Amẹrika tun sọ ni pe o ṣeṣe ki Biden bori Trump ni ọna ara ti awọn eeyan ko lero.

Eyii to n tumọ si pe, kii ṣe pe Biden bori Trump nikan, ṣugbọn o gbo ewuro soju Trump lọna ti awọn eeyan ko lero.

Ni nnkan bi ọjọ diẹ si idibo naa ni arun Covid-19 lekenka si l'Amẹrika, eyii to mu Biden sọ ninu ọkan lara ipolongo rẹ pe Trump ti kuna nipa eto ilera ilẹ Amẹrika.

Yatọ si eyii, lara awọ nnkan ti awọn eeyan korira nipà Trump ni bo ṣe sọ pe oun fẹ kọ odi, eyii ti yoo dena mọ awọn to n wọle sorilẹ-ede naa lọna aitọ.

Bẹẹ lo tun sọrọ alufaṣa si awọn Musulumi, to si pe awọn awọn kan lara wọn ni alakakiti ẹsin.