Shark Attack Australia: Arákùnrin òmùwẹ̀ kó s'ọ́wọ́ ẹja Sháàki, ikú ló padà já sí

Aworan ọkọ ọlọpaa niwaju omi okun tawọn eeyan ti n wẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arakunrin kan ti ka'gbako iku lọwọ ẹja Shaaki kan lasiko to n wẹ ninu okun lagbegbe iwọ oorun Australia.

Nibi omi okun kan to wa ni Cable Beach ni apa ariwa ipinlẹ naa lẹja yi ti ṣe ikọlu sii.

Iroyin sọ pe wọn ribi gbe ọkunrin naa kuro ninu omi ṣugbọn o pada gbẹmi mi.

Atẹjade kan lati ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Western Australia sọ pe ''Ile iṣẹ ọlọpaa ri aridaju lati fi di ọrọ mulẹ pe arakunrin ti a n wi yi ti padanu ẹmi rẹ''

Wọn ti ti aaye ibi igbafẹ lẹgbẹ okun ti iṣẹlẹ naa ti waye bayi pẹlu ikilọ kara ilu yago fun wiwẹ ninu omi naa.

Lọdun yi nikan, eeyan mẹjọ ni ẹja shaaki ti bujẹ ti wọn si gba ibẹ ku.

Shark

Wọn ti bẹrẹ si ni tọ pinpin shaaki aṣukupani yi ṣugbọn wọn ko mọ pato iru ẹya tii ṣe.

Ajọ to n tọju ayika ẹni Taronga Conserbvation Society sọ pe o kere tan eeyan mejilelogun ni shaaki ti bujẹ lọdun yi kan naa.

Amọ, wọn ni o ṣọwọn ki shaaki ṣe ikọlu sawọn eeyan to wa wẹ lodo Cable Beach to wa lẹba ilu Broome.

Arakunrin kan to n taja lẹgbẹ ibi igbafẹ yi sọ fun ileesẹ iroyin ABC pe ''iru nkan bayi sọwọn ti o si fọwọ kan ni lẹmi''

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́