Aláìsàn Covid-19 fìbínú lù aláìsàn ẹgbẹ́ rẹ̀ pa nítorí pé ó ń gbàdúrà lẹ́gbẹ́ rẹ̀ nílé ìwòsàn

File photo of hospital room

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arakunrin alaarun Covid-19 ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan ti lu alaisan mii ti wọn jijọ n gba itọju nile iwosan pa.

Ki lohun to mu iṣekupani yii wa? O ni o n gbadura lẹgbẹ ohun nile iwosan lo ba fi akoto ti wọn fi afẹfẹ 'oxygen' sinu rẹ lu u titi to fi ku.

Ileeṣẹ ọlọpaa Los Angeles ni Jesse Martinez faraya nigba ti alarun ẹni ọdun mejilelọgọrin kan to wa lẹgbẹ rẹ bẹrẹ si ni gbadura.

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Inu bi i debi pe o gbe kondoro ti ọxygen wa ninu rẹ to si fi lu agbalagba naa.

Lọjọ keji ni ẹni ti wọn lu yii pada gba ibẹ ku.

Awọn mejeeji ti ọlọpaa sọ pe wọn ko mọra ti tẹlẹ jijọ n gba itọju ni iyara ẹlẹni meji nile iwosan Antelope Valley Hospital to wa ni Lancaster, California.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Afurasi naa bẹrẹ si ni binu nigba ti baba yi n gba adura. Lẹyin naa lo ba gbe kondoro oxygen to si laa mọ lori''.

Atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti ''fi ẹsun ipaniyan, wiwu iwa inunibini(hate Crime) ati ikọlu si agbalagba kan afurasi naa Jesse Martinez''

Lọwọlọwọ awọn ile iwosan California n tiraka lati le tọju awọn miliọnu kan eeyan to lugbadi Covid-19 laarin ọsẹ mẹfa pere.

O ti le ni awọn eeyan miliọnu meji to ti ko arun naa bayi lati igba ti ajakalẹ Covid-19 bẹrẹ.