2nd wave of Covid-19: Wo bí àjọyọ̀ ọdún ṣe lè wáyé ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ lọ́dún yìí lábẹ́ àwọn òfin tuntun nípa COVID-19

Oríṣun àwòrán, Gboyega oyetola/twitter
Wo bi ajọyọ ọdun ṣe lee waye ni ipinlẹ rẹ labẹ awọn ofin COVID-19 tuntun
Opin ọdun de, pọpọṣinṣin ọdun tẹlee, bẹẹni ipenija ati ipaya nipa ọwọ keji ajakalẹ aarun COVID-19 naa ko gbẹyin; gbogbo rẹ lopin ọdun 2020 yii naa ni.
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
- Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe "Carnival" lòdì sí òfin Covid-19 tuntun yóò fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun
- Kílódé tí Twitter fẹ́ jẹ ojú àwọn tó ń "follow" Trump kí wọ́n tó gbé Twitter ìjọba Amẹ́ríkà lé Biden lọ́wọ́?
- Wo ohun tí Pasuma sọ nípa Opeyemi, ọmọ rẹ tó di ọmọ ogun orí omi l'Amẹrika
Ni iru asiko yii, kaakiri agbaye lawọn eeyan yoo ti maa minijọjọ kiri ti wọn yoo si maa gbaradi fun oniruuru ipejọpọ pọpọṣinsin ọdun eleyii ti ko ni ri bẹẹ lọdun 2020 bayii nitori awọn akọtun iṣẹlẹ ajakalẹ aarun COVID-19 lagbye bayii, ti ko si yọ Naijiria silẹ.
Idi niyi ti awọn ijsba lẹkajẹka, ipinlẹ ati ti apapọ pẹlu ṣe ti gbe awọn aṣẹ kan silẹ fun titẹle lasiko ọdun yii ki ajakalẹ arun naa ma baa di tọrọ fọkale lorilẹede Naijiria.
Eyi ni awọn igbesẹ tawọn to wa ni ijanu iṣejọba lawọn ipinlẹ to wa lẹkun iwọ ooru gusu orilẹede Naijiria gbe lati dena ọwọja aarun COVID-1
Ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, Twitter/rotimi akeredolu
Ipinlẹ Ondo wa lara awọn ipinlẹ to kọkọ gbe igbesẹ lori ilana bi awọn olugbe ipinlẹ naa yoo ṣe ṣe ọdun si.
- Ko ni si eto isin aisun ọdun.
- Awọn iṣẹ isin ọdun ọdun ku ọla to maa n waye ni aṣalẹ ọjọ kọkanlelọgbọn ko gbọdọ ju agogo mẹwaa alẹ lọ.
- Iwọle gbogbo ileewe alakọbẹrẹ ati girama ni ipinlẹ naa di ọjọ kejidinlogun oṣu kini ọdun 2021.
- Awọn ọja yoo ṣi maa wa ni ṣiṣi ṣugbọn okun amojuto nib yoo ṣi lewọ sii
- Awọn ile igbafẹ, ile ijo gbogbo ko gbọdọ ṣiṣẹ kọja agogo mẹwaa aṣalẹ lọ.
Ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, Twitter/rotimi akeredolu
Iwọgile awọn ayẹyẹ Keresimesi ati opin ọdin gbogbo bii adura aisun ọdun, ayẹyẹ ọlọpọ ero Carnival, pẹlu ayẹyẹ wẹjẹwẹmu gbogbo.
- Gbogbo ileewe yoo wa ni titipa titi di ọjọ kejidinlogun ọdun 2021.
- Awọn ileejo, ile igbafẹ, gbogbo naa yoo wa ni titi pa titi di ọjọ ti ijọba yoo kede to ba ya.
- Awọn ileejọsin ko gbọdọ gba ju eeyan aadọta lọ
- Laarin agogo mẹjọ aarọ si mẹrin irọlẹ lawọn ọja yoo maa wa ni ṣiṣi.
- Ilaji iye ero to yẹ lawọn ọlọkọ, ọlọkada maa ko ni wọn yoo maa ko bayii. Iyẹn nipe ọkọ to n ko eeyan mẹfa yoo bẹrẹ si ni ko eeyan mẹta ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Gboyega akosile/twitter
Lẹyin ti gomina ipinlẹ naa ti lugbadi aarun COVID ti iroyin si tun ti n fihan pe iye awọn to n ko aarun naa lojoojumọ tunt ti n peleke sii gẹgẹ bi awọn agbejade ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣe n gbe e jade lojojumọ ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gbe awọn ilana akọtun sita ti yoo de bi ọrs pọpọṣin'sin ọdun yoo ṣe lọ ni ipinlẹ naa.
Lara awọn ilana to gbe kalẹ ree.
- Ko ni si aye fun ipejọpọ lasiko keresimesi.
- Ijọba ipinlẹ Eko ti awọn ile ijo gbogbo pa
- Ilana tuntun lori bi awọn ile ijọsin yoo ṣe maa ṣe iṣẹ isin wọn.
- Awọn ileejo, ile igbafẹ, gbogbo naa yoo wa ni titi pa titi di ọjọ ti ijọba yoo kede to ba ya.
Ipinlẹ Ọṣun.

Oríṣun àwòrán, Gboyega oyetola/twitter
Laipẹ yii ni awọn oluwadi ijinlẹ nipa kokoro arun ni ibudo iwadi imọ igbalode nipa kokoro arun to wa lọgba fasiti Redeemers University ni ilu Ẹdẹ pariwo sita pe o jọ bi ẹni pe ẹya tuntun kokoro aarun COVID-19 ti wọ ipinlẹ Ọṣun eleyi to ko jinijini bo ọpọ.
Ijọba ipinlẹ naa gbe awọn ilana kan kalẹ lati rii daju pe wahala ajakalẹ arun naa ko tun burẹkẹ lẹẹkeji.
- Ijọba wọgile eto kika wakati wọ inu ọdun tuntun, New Year Countdown ti wọn maa n ṣe nibẹ
- Ilaji iye ero to yẹ lawọn ile igbafẹ, ile ijo ni wọn yoo maa fi aye gba bayii. Iyẹn nipe ile ijo to ba yẹ ko gba ọgọrun eeyan yoo bẹrẹ si ni fi aye silẹ fun iwọnba aadọta eeyan pere.
- Gbogbo awọn ilu ati ileto ni wọn paṣẹ fun ko dawọ awọn ayẹyẹ ati ajọdun ọlọdọọdun wọn duro
- Eto isinku, isọmọlorukọ, igbeyawo gbọdọ wa ni adinku bayi na.
Ipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, Twitter/gboyegaakosile
Ipinlẹ Ekiti naa ko gbẹyin ninu igbesẹ ilana lati wa ọwọ ajakalẹ arun COVID-19 to tun fẹ maa gbẹnu soke bayii bọlẹ.
- Eto isin kan ṣoṣo ni aye wa fun fun ọkan o jọkan awọn ẹlẹsin ni ọjọ Ẹti, ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku.
- Awọn alaṣẹ ti fun awọn agbofinro laṣẹ lati fi idi awọn ilana tuntun naa mulẹ.
- Awọn oṣiṣẹ to wa ni akasọ kejila iṣẹ ọba wa sisalẹ yoo joko sile di ọjọ kejidinlogun ọdun 2021 nigba ti wọn yoo gba idari lori asiko ti wọn yoo wọle pada sẹnu iṣẹ.
- Awọn ileewe yoo di titi pa di ọjọ kejidinlogun ọdun 2021
- Iṣọ oru, ile ijo ati ile igbafẹ yoo di titipa titi di igba ti ijọba ba to tun kede.












