#BeyondFakeNews: Ẹ ta kété sí ìròyìn òfégè

Aarẹ Muhammadu Buhari ti funpe si awọn oniṣẹ lorilẹede yii lati ṣe afikun akitiyan nipa sisọ iroyin to ṣee gbẹkẹle ki wọn si yago fun sisọ ayederu iroyin.
Aarẹ n sọ eyi nigba ti oludari agba patapata ti ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ BBC, Jamie Angus ṣebẹwo si i nile ijọba, aarẹ Buhari sọ pe aridaju lo gbudo kun inu gbogbo iroyin wọn.
O ki ile iṣẹ iroyin BBC ku oriire fun iyi ti wọn n ri gba lasiko ti ilu le bii igba ogun nilẹ Naijiria.
Aarẹ jẹ ko di mimọ pe nipa wiwa aaye ati ohun elo lati ṣewadii awọn iroyin wọn ki wọn to gbe e sita.

O ni BBC ti gba oriyin fun pe o jẹ ile iṣẹ to n sọ iroyin ti ko lẹja mbakan ninu ti awọn eniyan si gbara le fun iroyin otitọ nipa ohun kohun to n sẹlẹ lode.
Bakan naa, aarẹ kan sara si ifara jin BBC lati tan iroyin kalẹ ni ede Hausa kaakiri ẹkun rẹ ati bi wọn ṣe tun bẹrẹ iroyin lede Igbo, Yoruba ati Pidgin lorilẹede Naijiria.

Ikọ BBC wa ṣalaye awọn aato wọn lati ṣe agbejade iroyin gbogbo idibo to n bọ lorilẹede Naijiria to fi mọ alaye nipa gbogbo ipade itagbangba pẹlu awọn oludije gomina.










