Lagos APC Rally: MC Oluọmọ kò kú, irọ́ nìròyìn tó ń tàn kálẹ̀

Musiliu Akinsanya

Oríṣun àwòrán, Instagram/mcoluomo

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan Oluomo sọrọ lori ilera rẹ

Ibeere ti ọpọ eeyan n beere bayii ni pe ipo wo gan an ni Musiliu Akinsanya ti gbogbo eniyan mọ si MC Oluọmọ wa lẹyin to fara gbọgbẹ nibi wahala ipolongo ibo APC to waye nipinlẹ Eko.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe o ṣeeṣe ki wọn gbe MC Oluọmọ lọ si oke okun lati lọ tẹsiwaju itọju rẹ.

A tun gbọ wi pe wamu wamu ni awọn ọlọpaa duro pẹlu ọkọ bi mẹta siwaju ile iwo Eko ti MC Oluomo ti n gba itọju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, ọkan lara awọn to sun mọ Akinsanya ti wọn n pe ni kokozaria ti sọrọ laarọ ọjọ Ẹti loju opo Instagram rẹ irọ ni iroyin to n tan kaakiri pe MC Oluomo ti papoda.

Musiliu Akinsanya

Oríṣun àwòrán, Instagram/kokzaria

Àkọlé àwòrán, Ọrọ ilera Musilu Akinsanya

Kokozaria ki gbogbo eeyan to n fi adura ran MC Oluomo lọwọ nibi to ti n gba itọju nile iwosan. O ni awọn ọta rẹ ni ti wọn fẹ ko ku ni wọn n gbe iroyin naa kiri.

Kokozaria fi kun ọrọ rẹ pe ọgbẹni Akinsanya ni wọle gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awakọ onimọtọ nipinlẹ Eko.

MC Olumomo pẹlu kokozaria

Oríṣun àwòrán, Instagram/kokzaria

Àkọlé àwòrán, Ọrọ ilera Musilu Akinsanya

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti kede tẹlẹ pe awọn wọn n wa ọkunrin kan, Mustapha Adekunle, ti inagijẹ rẹ n jẹ seigo.

Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe wọn fi ẹsun kan Seigo ni pe o gbiyanju lati da eto ipolongo ibo ita gbangba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ṣe nipinlẹ naa.

Lara awọn ti ọta ibọn ba ni oniroyin kan lati ileeṣẹ iwe iroyin the Nation, Emmanuel Oladesu, Temitọpẹ Ogunbanke lati iwe iroyin NewsTelegraph pẹlu ayaworan ileeṣẹ mohunmaworan Ibilẹ Television, Abiọdun Yusuf atawọn eeyan miran.

Lori eyi, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa l'Eko, Chike Oti ninu ikede kan to fi sita sọ pe lọgan ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn gbe Oluọmọ ati awọn mii to tun farapa lọ si ileewosan fun itọju.

Ati wi pe ki awọn ara ilu fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti ti wọn ba gbọ ohunkohun tabi mọ ibi ti arakunrin Mustapha Adekunle ti wọn fi ẹsun kan wa.