BBC Debate: Abdulrahaman, Olùdíje APC yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ìtagbangba BBC ní Kwara

Abdulrazak Abdulrahaman

Oríṣun àwòrán, apc kwara media

Àkọlé àwòrán, Abdulrahaman Abdulrazak ní òun yóò máa ṣàlàyé ìdí tí òun kò fi ní kópa lọ́jọ́ iwájú

Ni ọjọbọ, ọjọ kẹwa oṣu kini ọdun 2019 ni ipade ifọrọwerọ itagbangba laaarin awọn oludije ipo gomina nipinlẹ Kwara atawọn araalu, yoo waye nilu Ilọrin.

Amọṣa, awọn eeyan ipinlẹ Kwara ko ni lanfani lati gbọ ọrọ lẹnu oludije ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ti o ti han gbangba pe ko ni wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Abdulrazak Abdulrahaman to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fi iwe ranṣẹ si ileeṣẹ iroyin BBC news Yoruba ni ọ̀jọ́ diẹ si asiko ti eto naa yoo bẹrẹ pe ohun ko nilee wa ati pe oun yoo maa sọ fun awọn eeyan ipinlẹ naa lọjọ iwaju idi ti oun ko fi lee wa.

Abdulraham jẹ ọkan lara awọn oludije mẹrin ti awọn eeyan fi ibo ori ayelujara gbe kalẹ pe awọn fẹ gbọ t'ẹnu rẹ nibi ipade ifọrọwerọ itagbangba naa eleyi ti ileeṣẹ BBC news Yoruba gbe kalẹ lati fi mu oju aje konisọ laaarin awọn oludije to fẹ di gomina atawọn araalu ti wọn yoo ṣejọba le lori.

Àkọlé fídíò, Kwara yóò gbàlejò BBC Yoruba

"Iyalẹnu lo jẹ fun mi pe ileeṣẹ iroyin BBC bẹrẹ si nii polongo orukọ mi gẹgẹ bii ara awọn ti yoo farahan nibi ipade ifọrọwerọ ọjọbọ nigba ti n ko fi igba kankan sọ fun wọn pe maa wa."

Gbogbo ọna to yẹ ni yiyẹ ni ileeṣẹ BBC News Yoruba yẹ lati kan si gbogbo awọn oludije tawọn araalu mu pe awọn fẹ ri nibi ipade naa.

Koda, ileeṣẹ BBC News Yoruba tun kan si Minisita feto iroyin, Lai Mohammed, to jẹ eekan ati aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Kwara lori ipe ti a fi ranṣẹ si Oludije ẹgbẹ oṣelu naa; ti minisita feto iroyin pẹlu si tun fi idaniloju lelẹ pe yoo farahan nibi eto ọhun.