#BBCGovDebate: Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú ANRP ní ìpínlẹ̀ Kwara ṣèlérí fáwọn obìnrin

Yinka Ajia to jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ANRP ni awọn yoo fi ọrọ obinrin ṣe pataki ninu ijọba.
"Lori ọrọ awọn obinrin, a má fún àwọn obìnrin ni idaji ipo alaṣẹ ijoba ti mo ba wọle"."A gbọ́dọ̀ dowo pọ̀ pẹlu awọn obinrin". Ó tẹ siwaju, "nidii iṣe ti a ba ṣe, a ma ṣi gbe ofin jade pe ida ọgbọn iṣẹ agbaṣe ijoba ni ko máa lọ sílè iṣẹ tó jẹ́ táwọn obinrin".

Bakan naa, oludije fun ipo gomina nipinlẹ Kwara labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Issa Arẹmu ti ni ipinlẹ Kwara n fi ebi ṣere bayii laimọ.
Nibi ipade ita gbangba ti BBC news Yoruba gbe kalẹ fawọn Oludije ipo gomina ni ilu Ilọrin ni Issa Arẹmu ti sọ ọrọ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni wahala to n ṣẹlẹ lagbegbe Saarẹ ati Ṣaragi ni ipinlẹ naa nibi ti aawọ ti n waye laaarin awọn agbẹ yoo fa ọda ounjẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa bi wọn ko ba tete wojutu sii.
Ija aala ilẹ laaarin awọn eeyan Ṣaarẹ ati Ṣaragi ti n fa ọpọ wahala ati ikayasoke ni agbegbe ọhun eleyii ti oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour naa ṣalaye pe o ṣee ṣe ko fa ọwọgogo ounjẹ ni ipinlẹ ọhun.
O ni bi oun ba lee de ipo gẹgẹ bii gomina nibẹ, ara awọn nnkan ti oun yoo mu gbọ naa ni bi alaafia yoo ṣe pada jọba lagbegbe naa ki iṣẹ agbẹ lee gbilẹ fun ipese ounjẹ fun araalu.

'Gbèsè tí Kwara jẹ, kò leè san án tán l'ógún ọdún'
Ọkan lara awọn oludije to n dije fun ipo gomina nipinlẹ Kwara, Ayọrinde Adedoyin ti ṣalaye pe, gbese to wa lọrun ijọba ipinlẹ naa bayii yoo to ogun ọdun ki wọn to rii san tan.
Adedoyin to n dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Accord sọ eyi di mimọ nigba to n dahun ibeere lori eto ipade ita gbangba fawọn oludije to waye nilu Ilọrin.

Adedoyin ni, nibi ti ọrọ de duro bayii, gbese ti awọn iṣejọba ni ṣisẹ-n-tẹle nipinlẹ Kwara ti jẹ bayii le ni aadọta biliọnu naira ni ilẹ yii ati aadọta miliọnu dọla owo ilẹ Amẹrika fun gbese oke okun, leyi to ni yoo nira lati san tan ni ogun ọdun si asiko yii pẹlu bi o ṣe jẹ pe biliọnu meji naira o din diẹ ni owo to n wọle sapo ijọba labẹle.
Awọn oludije yooku pẹlu ni ki nnkan to lee jọju fawọn eeyan ipinlẹ Kwara, ijọba gbọdọ wa nnkan ṣe si ọrọ owo to n wọle.

Kíni ohun t'áwọn olúdíje sọ gan an?
Kini ohun tawọn oludije kọọkan n sọ ni ibi ipade itagbangba to n waye lọwọ fawọn oludije ipo gomina nipinlẹ kwara;
Ayọrinde Adedoyin

- Kwara gbọdọ kọkọ yẹ ara rẹ wo lati mọ ibi ta wa. Wọn ni awa ni a wa ni ipo kejidinlọgbọn.
- Ni igba ibẹẹrẹ, eto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara n lọ geerege ati eto abo wa ni ilẹ Kwara tẹlẹ laisi idigunjale, ti a kii si mọ ogiri yíká ilé wa.
- Loni, kò sì ilé ese mo kò Kwara, ile igbafẹ nikan ni a n kọ.
- Tá bá wo ohun tá ni Kwara àti nkan tá ń rí nibe, ó ń pá wá lekun. Ohun tá ń lọ wo ni Kenya bíi irinajo afé wá ní Naijiria bíi old Oyo National park. A ní láti ṣe ọna ti ara ilu yóò gbà de ibè ni.
- Táwọn oyinbo bá dé, tí wọn rí ohun tá tí ṣe, àwọn náà yóò gbé owó kalẹ.
- Àwọn èèyàn yóò lè lọ kólé si awon ibudo irin ajo igbafé bíi Esie.
Issa Aremu


- A lee gbìn òwú ni Kwara torí pé a ní ileese tó ń ṣe aṣọ láyé ìgbà kan.
- A ni ilẹ to ni ọra ṣugbọn, Ṣé ni wọn ń kó owó Kwara fún àwọn àgbè aláwò funfun ni oko songi.
- Ohun ti a wa fẹ ṣe bayii ni lati gbe awọn agbẹ tiwa ni ipinlẹ Kwara larugẹ lati ṣiṣẹ fun awọn eeyan wọn dipo awọn alawọ funfun.
Yinka Ajia

- Lẹyin ilera, eto ọgbin lo kan. A ri i pe a ko ṣe àmúlò àwọn ilẹ wa to bi o ti yẹ mọ lati fi
- Ati pe a ko ni gbà owó orí lọwọ àwọn èèyàn nígbà tí wón kó ni owo lọ́wọ́.
- A ko ni ra aloku ọkọ mo ní Kwara, tuntun là o máa ra tí mo bá wole.
- Lori irinajo igbafẹ, kò sì ijoba ibilẹ kankan ní Kwara tí kò ní ibudo irinajo afẹ.
- Maa mú eka aladani wá láti ṣe irinajo igbafé èyí tí yóò mú ìṣe wá fáwọn odò.

Eto ipade itagbangba naa waye ni gbọngan fasiti ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara.
Wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́, àwọn oludije ti n de si gbọngan ti eto naa yoo ti waye bẹ́ẹ̀ si ni àwọn olukopa naa ti n gunlẹ̀.

Awọn ẹgbẹ oselu marun un to lewaju to si yẹ ko kopa ni ẹgbẹ oselu PDP, APC, Accord, Labour ati ANRP.
Ṣugbọn o ku diẹ́ ki eto naa waye ni Olùdíje APC yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ìtagbangba BBC ní Kwara nitori naa, awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ni PDP, Accord, Labour ati ANRP.

Awọn asoju ẹgbẹ oselu ọhun ni Ọmọọba Ayọrinde Adedoyin ti ẹgbẹ oṣelu Accord, Komuredi issa Arẹmu, ti ẹgbẹ oṣelu Labour,
Asofin Abdulrasak Atunwa, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, ati Ọmọwe Abdulmunin Yinka Ajia, ti ẹgbé oṣelu ANRP.
Bakan naa, digbi ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Kwara to fi mọ awọn oṣiṣẹ alaabo wa lati ṣamoju to abo ninu gbọngan ati lagbegbe eto naa.













