Ẹ wo bí ìjíròrò ṣe lọ láàrin àwọn olùdíje gómìnà Kwara
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ẹ wo ìpàdé ìtagbangba BBC News Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Kwara bó ṣe ń lọ lọ́wọ́-lọ́wọ́:
Skip Facebook post
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Kini ohun tawọn oludije kọọkan n sọ ni ibi ipade itagbangba to n waye lọwọ fawọn oludije ipo gomina nipinlẹ kwara;
Ayọrinde Adedoyin

- Kwara gbọdọ kọkọ yẹ ara rẹ wo lati mọ ibi ta wa. Wọn ni awa ni a wa ni ipo kejidinlọgbọn.
- Ni igba ibẹẹrẹ, eto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara n lọ geerege ati eto abo wa ni ilẹ Kwara tẹlẹ laisi idigunjale, ti a kii si mọ ogiri yíká ilé wa.
- Loni, kò sì ilé ese mo kò Kwara, ile igbafẹ nikan ni a n kọ.
- Tá bá wo ohun tá ni Kwara àti nkan tá ń rí nibe, ó ń pá wá lekun. Ohun tá ń lọ wo ni Kenya bíi irinajo afé wá ní Naijiria bíi old Oyo National park. A ní láti ṣe ọna ti ara ilu yóò gbà de ibè ni.
- Táwọn oyinbo bá dé, tí wọn rí ohun tá tí ṣe, àwọn náà yóò gbé owó kalẹ.
- Àwọn èèyàn yóò lè lọ kólé si awon ibudo irin ajo igbafé bíi Esie.
Issa Aremu

- A lee gbìn òwú ni Kwara torí pé a ní ileese tó ń ṣe aṣọ láyé ìgbà kan.
- A ni ilẹ to ni ọra ṣugbọn, Ṣé ni wọn ń kó owó Kwara fún àwọn àgbè aláwò funfun ni oko songi.
- Ohun ti a wa fẹ ṣe bayii ni lati gbe awọn agbẹ tiwa ni ipinlẹ Kwara larugẹ lati ṣiṣẹ fun awọn eeyan wọn dipo awọn alawọ funfun.
Yinka Ajia

Oríṣun àwòrán, AFP
- Lẹyin ilera, eto ọgbin lọ kan. A ri pe a ko ṣe àmúlò àwọn ilẹ wa to bi o ti yẹ mọ lati fi
- Ati pe a ko ni gbà owó orí lọwọ àwọn èèyàn nígbà tí wón kó ni owo lọ́wọ́.
- A ko ni ra aloku ọkọ mo ní Kwara, tuntun là o máa ra tí mo bá wole.
- Lori irinajo igbafẹ, kò sì ijoba ibilẹ kankan ní Kwara tí kò ní ibudo irinajo afẹ.
- Maa mú eka aladani wá láti ṣe irinajo igbafé èyí tí yóò mú ìṣe wá fáwọn odò.








