Oyo 2019 Budget: Ìjọba Ọyọ gé ₦282bn owó ìsúná 2019 sí ₦181bn

Abiola Ajimobi n gbe iwe isuna kalẹ siwaju ile asofin

Oríṣun àwòrán, Oyo Assembly

Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ ti ge owo isuna ọdun 2019 lati biliọnu lọna ọrinlerugba ati meji naira (N282 billion) si biliọnu mọkanlelọgọsan (N181 billion) Naira.

Ọjọ Kẹta, Osu Kẹsan, ọdun 2019 ni Ile Igbimọ Asofin ipinlẹ Ọyọ buwọlu abadofin ti yoo se agbeyẹwo owo isuna ọdun 2019, ti awọn asofin si gba aba naa wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Abẹnugan Ile Asofin Ipinlẹ Ọyọ, Adebo Ogundoyin ni ijọba ana ko se dara to lori eto isuna ọdun 2019, ati wi pe kii se abadofin to le wa si imusẹ ni ipinlẹ naa.

Ọsẹ to kọja ni Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde sọ wi pe eto isuna ti gomina ana, Abiola Ajimobi se kii se isuna ti awọn le e sisẹ le lori.