Oyo State: Ètò ìṣúná ìpínlẹ́ Oyo yóò jẹ láti ìbẹrẹ de òpin ọdún

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Akọwe agba ijọba ipinlẹ Ọyọ, Iyaafin Olubamiwo Adeosun ti ṣalaye pe Ipinlẹ naa yoo pada bẹrẹ si ni jẹ awokọse fun awọn toku.

O ni gbogbo eto lo ti wa nilẹ lati ṣamulo eto Iṣuna Ipinlẹ naa lọna to yẹ ni ibẹrẹ ọdun si opin ọdun.

Akọwe agba yii lo sọ orọ naa ni ọjọbọ ọsẹ yii ni ilu Ibadan nibi ti o ti n ṣe idanilẹkọ lori eto Amuyẹ Iṣuna .

O tẹpẹlẹ mọ iṣamulo ati igbelarugẹ alakalẹ eto iṣuna to ye kooro lojuna ati da awọn eekan ninu iṣẹ ijọba lẹkọ ninu isẹjọba Makinde.

Adeosun ṣalaye iṣuna ijọba bii eyi ti o n ṣe afihan eto ti ijọba ni fun idagbasoke awujọ.

Ko ṣai mẹnuba pataki ti eto iṣuna n ko ninu ọrọ aje ati inawo fun idagbasoke ilu.

O wa gba awọn oṣiṣẹ naa ni imọnran lati ri ara wọn gẹgẹ bi oniṣowo ti o fẹ jere fun araalu.

Ninu ọrọ rẹ,o ni erongba ijọba ni lati pese ohun amuludun fun ara ilu sugbọn ti ilana eto iṣuna to peye yoo jẹ anfaani nla.

Aworan awon ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Oyo govt

Àkọlé àwòrán, Awon ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Oyo

Arabinrin naa gboriyin fun Gomina Makinde fun dida ile iṣe eto Iṣuna ti o gbominira lati ṣiṣẹ ti yoo si fa tolori tẹlẹmu mọra.

O tẹsiwaju pe,ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gunlẹ ilana eto iṣuna amuyẹ wọ ọdun 2020 .

Ninu ọrọ tirẹ, Olori awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa,Alhaja Ọlọlade Agboọla ṣalaye pe asiko imuṣofun iṣuna ti kọja.

Gẹgẹ bi o ti wi, o ni inakuna owo ijọba ko si mọ ni bi ijọba ti ṣetan lati gbajumọ awọn eto alakalẹ ẹ rẹ.

Gbongan Idanileko Ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt

Àkọlé àwòrán, Ibi idanileko ni Ibadan

Awọn eto alakalẹ naa ni ; eto Ekọ, Ilera, eto aabo ati ọrọ aje ti ijọba yoo ri wi pe o de ẹsẹ kuku kaakakiri ipinlẹ naa.

Nigba ti kọmiṣọnna fun eto Iṣuna ati Ọrọ Aje lpinlẹ naa, Amofin Adeniyi Farinto n ṣalaye fun awọn akọroyin, o ni gbogbo eto naa ni yoo di mimu ṣe.

O ni ti o ba di opin ọdun yii , eto iṣuna ọdun 2020 yoo di fifi ṣọwọ si ile Igbimọ Aṣofin ki o to di fifọwọ si fun Gomina Makinde.