$9.6bn: Ilé ẹjọ́ ni Nàìjíríà lè takò ìdájọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé $9.6bn ohun ìní Nàìjíríà

Ontẹ ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ijọba Nàìjíríà fẹ́ kí ilé ẹjọ́ ó fagilé idajọ to ni ki wọn sanowo yi fun ile iṣẹ ilẹ Gẹẹsi naa

Ile ẹjọ kan nilẹ Gẹẹsi ti dajọ pe orileede Naijiria le tako idajọ lori owo itanran $9.6bn ti ileeṣẹ ilẹ Gẹẹsi kan P&ID fẹ ki Naijiria san fun un.

Lọjọbọ ni wọn gbe idajọ yi kalẹ lori ọrọ meji ti Naijiria gbe wa si iwaju ile ẹjọ naa.

Akọkọ rẹ ni pe Naijiria fẹ ki ile ẹjọ gba wọn laaye lati tako idajo naa.

Ẹlẹẹkeji ni pe wọn fẹ ki ile ẹjọ paṣẹ ki wọn dawọ duro lori amuṣẹ idajọ to ti waye ṣaaju pe P&ID le gba owo naa lọwọ Naijiria.

Lati nnkan bi ọjọ melo kan lawọn alaṣẹ Naijiria ti wa ni ilẹ Gẹẹsi lori ọrọ yii.

Ninu wọn la ri Minisita fọrọ idajọ Abubabakar Malami, ọga agba banki apapọ Godwin Emefiele ati Minisita feto iroyin Lai Mohammed.

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe ile ẹjọ ko tii dajọ lori abala keji ọrọ owo naa to jọ mọ pe ki wọn ma tii faaye gba ileeṣẹ P&ID lati gba owo pada.