Ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà ní 'Check Point' kàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ awakọ̀ l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inu ibanujẹ ni mọlẹbi Ripẹtọ Edighere Orhewere, ọga ọlọpaa ti awakọ akero kan fi ọkọ pa ni agbegbe Agbara nipinlẹ Eko.
Oloogbe Orhewere, to jẹ ẹni aadọta ọdun, ni iwe Iroyin jabọ pe oun ati awọn akẹẹgbẹ rẹ kan duro si kọọrọ kan lati ṣọ adugbo ni Agbara, ni awakọ danfo naa sọ ijanu ọkọ nu nitori ere asapajude, to si kọlu ọlọpaa naa lati ẹyin.
Wọn ni niṣe ni awakọ naa salọ, to si fi ọkọ rẹ silẹ sibi ti iṣẹlẹ yii ti waye.
Gbogbo igbiyanju awọn akẹẹgbẹ ọlọpaa naa lati ri i mu lo jasi pabo ni eyi to pada ja si iku fun agbofinro naa.
- Kínla! Ṣé olùkọ́ fásitì OAU míràn tún ti kó sí gbaga ìbálòpọ̀-fún-máàkì ni?
- Ọmọ ọdún márùn-ún, àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ - LASEMA
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ènìyàn lo ti sọnù nítorí àìsàn Iba Lassa ní Kano àti Ondo
- Ọmọ ọdún mẹ́wàá ń jẹ ìrora lẹ́yìn tí ọ̀gá tì í sínú iná àrò búrẹ́dì
Iroyin sọ pe oju ẹsẹ ni Ọga ọlọpaa naa, to jẹ baba ọlọmọ meje, ku nitori pe irin to wa niwaju ọkọ naa wọ ọ ninu egungun ẹyin ati ibadi rẹ.
Nibayii, wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si to wa ni ileewosan Gbogboogbo ilu Badagry.
A gbọ wi pe awọn ọlọpaa tọ ipasẹ ẹni to ni ọkọ, oun lo si ibi ti wọn juwe ile awakọ naa fun wọn.
Ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi de ibẹ, awakọ naa ati ẹbi rẹ ti ko kuro ni ile naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana sọ fun awọn akọroyin pe, wọn ṣi n wa awakọ naa to salọ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ni ibanujẹ lo jẹ fun awọn agbofinro pe wọn maa n padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ.
O ni o di dandan ki ajọ agbofinro ṣe ẹyẹ ikẹyin fun awọn olọpaa bii ti ẹ to ku loju iṣẹ.
Ati pe awọn mọlẹbi rẹ le bẹrẹ si ni ṣeto riri ajẹmọnu oloogbe gba lẹyin isinku.
Odumosu fi idaniloju han pe ọwọ yoo tẹ ọkunrin awakọ naa laipẹ laijinna.














