Coronavirus: Àìsàn yíì ti ràn dé Amẹrika, Thialand àti South Korea

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹ-ede China ti kilọ fawọn eeyan dawọ lilọ-bibọ si ilu Wuhan nibi ti aarun Coronavirusti ti ṣekupa eeyan mẹsan an.
Bakan naa ni ijọba ti sọ fawọn olugbe ilu naa ti wọn miliọnu mọkanla lati yago fun apejọ ti ọpọ eeyan wa.
Aarun naa ti n ran bi ina inu ọyẹ lati ilu Wuhan lọ si awọn ẹkun miiran ni China, ko da o ti ran de ilẹ Amẹrika, orilẹede Thailand ati South Korea.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìbẹ̀rù nípa Amotekun ló ń mú káwọn èèyàn kan máa wí ìwíkùwí - Soyinka
- Wo àwọn àdúgbò tí ìpínlẹ̀ Eko ti fòfin de ọ̀kadà àti Marwa
- Àwa ò ri lẹ́ta kankan gbà láti ọ̀dọ̀ Malami lóri ọ̀rọ̀ àwọn alága Kansu - Makinde
- Àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbẹ́jọ Trump tí yóò blrẹ̀ l'ọ́dọ̀ àwọn Sẹ́nétọ̀
- Mí ò le nífẹ̀ẹ́ obìnrin Nàìjíríà kankan mọ lẹ́yìn ti mo ti tọ́ obìnrin òyìnbó wò- Issa
Oji le lugba eeyan lo ti lugbadi aarun naa eyi to n ran lati ọunjẹ inu okun.
Igbakeji minisita eto ilera, Li Bin ṣalaye pe ijọba n ṣiṣẹ takuntakun lori idena aarun naa lati ma le ran sii mọ.
China ti kọkọ kilọ pe o ṣeeṣe ki aarun naa ran lati ẹnikan si ẹlomiran.
Àkíyèsí nípa àìsàn 'Coronavirus' tó ń ṣàkóbá fún bí a ṣe ń mí
Arun Coronavirusti, to tun n jẹ 2019-nCoV, to n ja rain ni ilẹ China lo ti di irawọ ọsan to n ba awọn agba lẹru bayii lorilẹede Najiria nitori ọsẹ to n se.
O ti le ni ọọdunrun eeyan to ti jẹ Ọlọrun nipe latipasẹ arun naa, eyi ti ibẹrubojo wa pe ọwọja rẹ lee tan de orilẹede yii.
Yoruba si ni o n bọ, o n bọ awọn laa dẹ de amọ lode oni, oju ni wọn n mu to. Ta ba si fẹ kiyesara nipa arun naa, o yẹ ka mọ ohun kan tabi meji nipa rẹ ati awọ̀n ọna ta lee gba dena rẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ohun to yẹ ko mọ nipa arun Coronavirusti:
- Coronavirus maa n jẹ ki o soro fun eniyan lati mi daadaa, tabi mi kanlẹ
- Agbeegbe Wuhan ni orilẹede China ni wọn ti kọkọ gbọ nipa aisan naa.
- Ni bayii, eniyan mẹrin lo ti ku, ti o si ti ran oṣiṣẹ eleto ilera mẹẹdogun ni orilẹede naa.
- Ki i ṣe awọn oniṣẹ ilera nikan ni aisan naa ti ran, igba eniyan lo ti ni arun yii lara lati Osu Kejila, ọdun to kọja.
- Nitori naa ni awọn eniyan ṣe n woye pe ṣe aisan yii kii ṣe ohun ti eniyan gbọdọ bẹru lati ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ Ajọ Eto Ilera ni Agbaye, WHO ti ni, Ọjọ Kejilelogun, Osu Kini, ọdun 2020 ni awọn yoo ṣe ipade lori boya awọn yoo ka aisan naa si arun bii Ebola ati aisan ẹlẹdẹ ' Swine flu '.
Kini Aisan Coronavirus?
- Aisan Coronavirus ma n ran lati ara eniyan kan si ẹlomiran.
- Eleyii ni iwadii fihan pe o ran awọn oniṣẹ ilera to n fun awọn to ni aisan naa ni itọju
- Coronavirus jẹ ẹka aisan ti o ma n fa aisan Pneumonia ati awọn aisan ibalopọ miran
- Lara awọn aisan to n wa lati ara arun Coronavirus ni Sars, lati ara Sars (lati ara Bamboo) ati Mers (lati ara ẹsin), amọ iwadii si n lọ lọwọ lori ibi ti aisan eleyii ti san wa.
Kini akiyesi ti awọn eniyan gbọdọ mojuto?
Awọn oṣiṣẹ ilera ti kilọ fun awọn eniyan lati ṣe awọn akiyesi wọnyii, titi ti ọna abayọ yoo fi yọju nipa aarun naa.
- Bo imu rẹ ati ẹnu rẹ ti o ba n wukọ lati sin
- Ṣe ayẹwo finni-finni lati ṣere pẹlu ẹni to n wukọ tabi sin
- Fọ ọwọ rẹ pẹlu ọṣẹ ati omi lati igba de igba
- Ri daju pe o ṣe ẹfọ tabi ẹran daradara ki o to jẹ ẹ.

Njẹ ọna abayọ ti wa si aisan Coronavirus?
Ni bayii, ko tii si ọna abayọ si arun naa, amọ iwadii n lọ lọwọ lati ara awọn ti wọn ko arun naa lati wa ọna abayọ si arun Coronavirus naa.















