Oyo Algon: Ìjọba àpapọ̀ kò gbẹ́sẹ̀lẹ̀ lé owó tó tọ́ sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ l‘Ọyọ

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @Makinde Instagram

Àkọlé àwòrán, Ìpínlẹ̀ Oyo kò ri lẹ́ta kankan gbà láti ọ̀dọ̀ Malami lóri ọ̀rọ̀ àwọn alága Kansu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lórí ọ̀rọ̀ kan to gbà gboro kan pé àgbẹjọrò àgbà orilẹ̀-èdè Naijiria, Abubakar Malami ti paṣẹ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo láti gba àwọn alága kansu ti wọ́n yọ nípò pada, ijọba Ọyọ ti fesi lori isẹlẹ naa.

BBC Yoruba kan si akọwé ìkéde ìjọba ìpińlẹ̀ Oyo, Ọgbẹ́ni Taiwo Adisa lórí ọ̀rọ̀ náà sùgbọ́n o ni, ìrọ to jìnà si òtítọ ni nítori pé títí di àsìkò ti òun ń ba ilé iṣẹ́ BBC sọrọ, ko ti si lẹ́ta kankan to jọ bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Malami.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fí kun pé ko si ìgbà kankan ti Malami jáde láti sọ pe òun kọ lẹ́tà ránṣẹ́ si ìpínlẹ̀ Oyo, pẹlu afikun pe, o se pàtàki ki àwọn akọroyin máa ṣe ìwádìí wọ́n dáradára, ki wọ́n to maa tan ìròyìn ti ko fi ìdí múlẹ̀ káakiri.

Awọn alaga ijọba ibilẹ ni Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Ayodeji Abass Aleshinloye

Lori àhesọ ọ̀rọ̀ kan to sọ pé, ìjọba ìpinlẹ̀ Oyo ko rí owó gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpàpọ fún àwọn ìjọba ìbilẹ̀, nítori pé àwọn alaga fidiẹ ni wọ́n fi si ìjọba Kansu, Adisa ni ofo ọjọ keji ọja ni ọrọ ọhun.

" Ẹni ti wọ́n ba nà ló yẹ ki ara maa ta, tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ko ba ri owó gbà, ẹnu ìjọba ìpínlẹ̀ ni ẹ o ti gbọ ki ṣe ẹnu àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀. Nitorinaa, ofuutu fẹẹtẹ ni iroyin to ni awọn ijọba ibilẹ ni Ọyọ ko ri owo to tọ si wọn gba lati ọdọ ijọba apapọ."

Makinde, dá àwọn alága ìjọba ìbilẹ̀ padà sípò- Abubakar Malami

Malami & Makinde
Àkọlé àwòrán, Makinde, dá àwọn alága ìjọba ìbilẹ̀ padà sípò- Abubakar Malami

Agbẹjọ́rò àgbà àti mínísita fun ètò ìdájọ, Abubakar Malami ti pàṣẹ̀ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde láti ṣe àyipada ìpinnu rẹ̀ lóri bo ṣe tú àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ká ni ìpínlẹ̀ Oyo.

Èyí wáyé nínú lẹ́ta ti o fi síta ni ọjọ kẹrinlá, oṣù kínní 2020, ránṣẹ́ sí agbẹjọrò àgbà àti kọmisọna ètò ìdájọ ni ìpínlẹ̀ Oyo.

Lẹ́tà to pe àkọlé rẹ̀ ní yíyọ àwọn Gómìnà ti wọ́n dìbò yan lọ́nà àitọ àti yíyan àwọn ìgbìmọ̀ alábojúto, titẹ̀lé ìdájọ di dandan.

Agbẹjọrò ìjọba àpàpọ ní ìpínnu ilé ẹjọ to gajù lọ ti fofin de gbogbo ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rìnrìndílógoji.

O ni: " Àṣà àwọn gómìnà ni láti maa da àwọn alága ijọba ìbilẹ̀ sílẹ̀ ti wọ́n ba ti de ori òye, èyi ko ba òfin mu rárá."

Àkọlé fídíò, Farms to You: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

Malami ni: " Mo bẹ gbogbo àwọn gómìnà ìpińlẹ̀ àti àwọn àbẹnugan ilé ìgbimọ aṣòfin ti wọ́n ń tẹ òfin ọdun 1999 lóju, ti wọn n ṣe àigbọràn si ilé ẹjọ to ga jùlọ.

O ni pe o ṣe pàtàkì láti ṣe àtúnṣe to tọ ki wọn si dá wọ́n pada si ori oyè lojuna a ti fun àfin láàye ki wọ́n si ràn ìjọba awa ara wa lọ́wọ́."

Àkọlé fídíò, Hepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

" O ṣe pàtàkì láti tú gbogbo ìgbìmọ̀ alabojuto náà ka ki wọ́n sì dá àwọn alága ti wọ́n dìbò yàn pada sori oyè.

Ẹ̀wẹ̀, akọwé ìkéde fún gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisa ni àwọn ko ri lẹ́ta kankan láti ọ̀dọ̀ agbẹjọro àgbà Naijiria.

O fí kun pé ti lẹ́ta naa ba ti tẹ àwọn lọ́wọ́, ìjọba yoo gbe ìgbésẹ̀ to ba yẹ.