Trump impeachment: Àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbẹ́jọ Trump lọ́dọ̀ àwọn Sẹ́nétọ̀

Oríṣun àwòrán, EPA
Fun igba kẹta ninu ìtàn, aarẹ America kan n dojukọ igbẹjọ iyọnipo, ti igbẹjọ yoo si bẹrẹ ni ọjọ Iṣẹgin ni aago mẹfa irọlẹ.
Igbẹjọ naa le yọri si ki wọn o yọ Aarẹ Donald Trump kuro ni ipo. Abajade igbẹjọ yii yoo jẹ iyalẹnu.
Ibeere ati idahun meje ti yoo mu ki ẹ ni òye igbẹjọ naa niyii:
1) Kini ni iyọnipo tumọ si?
O jẹ eto to fi aaye gba awọn ọga ninu iṣẹ ijọba lati wadii awọn bi i adajọ, aarẹ ati awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ti ifurasi ba wa pe wọn ṣe aṣemaṣe ni ipo ti wọn wa.
Lẹyin ti wọn ba ti yọ ẹni naa ni ipo, yoo lọ fun igbẹjọ nile aṣofin agba. Nibẹ si ni awọn ọmọ ile yoo ti sọ boya o jẹbi tabi bẹẹkọ.
2) Ẹsun wo ni wọn fi kan Ọgbẹni Trump?
Ẹsun meji ni Trump n dojukọ: Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan an ni pe o n wa iranlọwọ ijọba Ukraine lati le pada bori ninu idibo aarẹ ti yoo waye l'oṣu Kọkanla.
Wọn fi ẹsun kan an pe o ko ọpọlọpọ miliọnu Dọla to yẹ ki wọn o fun Ukraine pamọ.
Ẹsun keji ni pe o n ṣe idiwọ fun iwadii ile aṣofin to n wadii rẹ fun iyọnipo lọdun to lọ, nitori pe ọọfisi aarẹ ko gba ki awọn oṣiṣẹ rẹ o jẹri niwaju ile aṣofin naa.
Ọgbẹni Trump sọ pe oun ko hu iwa buruku kankan.

Oríṣun àwòrán, Reuters
3) Kilode ti igbẹjọ yoo fi waye?
Awọn nkan yi lo mu ki ọrọ de ibi to de bayii:
- Oṣu Kẹjọ 2019: Atunilaṣiri kan fi ẹsun kan Aarẹ Trump
- Oṣu Kẹwaa si oṣu Kejila- Iwadii waye, pẹlu igbẹjọ nile igbimọ aṣoju-ṣofin (awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako Trump, Democratic lo n dari ile naa).
- Oṣu Kejila - Awọn olori ẹgbẹ oṣelu Democratic nile aṣoju-ṣofin dibo yọ Ọgbẹni Trump nipo
- Oṣu Kinni 2020 - Wọn ta a ri ẹjọ naa lọ si ile aṣofin agba (awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Ọgbẹni Trump, Republican n dari) nibi ti igbẹjọ yoo ti waye.
4) Bawo ni igbẹjọ ile aṣofin agba yoo ṣe ri?
Eniyan meji ni yoo sọ bi igbẹjọ naa yoo ṣe ri: Mitch McConnell, olori ẹgbẹ Republican nile aṣofin agba, ati akẹẹgbẹ rẹ, Chuck Schumer ti ẹgbẹ Democratic.
Awọn mejeeji ni yoo fẹnuko lori ilana fun ẹri, awọn ajẹri, ati asiko ti wọn yoo lo lori igbẹjọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣugbọn nitori pe awọn ọmọ ẹgbẹ Republican lo n dari ile aṣofin agba, Ọgbẹni McConnell lo ni aṣẹ lọwọ lori ọna ti igbẹjọ naa yoo gba.
Ọjọ Iṣẹgun ni awọn sẹnetọ yoo dibo lori awọn ilana igbẹjọ naa.
Lara awọn ilana to ti wa nilẹ ni pe: ko ni i si kikọ nkankan si ori ayelujara Twitter lati inu ile aṣofin lasiko ti igbẹjọ ba n waye.
Bakan naa ni awọn sẹnetọ ko gbọdọ ba awọn to ba joko si ẹgbẹ wọn sọrọ nigba ti igbẹjọ ba n lọ.
5) Awọn wo ni pataki ninu igbẹjọ naa?
Sẹnetọ kọọkan ti bura pe idajọ ododo ni awọn yoo ṣe lasiko igbẹjọ naa. Adajọ agba nile ẹjs to gajulọ.
John Robert si ni yoo dari igbẹjọ naa, botilẹjẹ pe awọn ọgọrun sẹnetọ naa ni yoo joko bi i adajọ ati ọmọ igbimọ igbẹjọ.
Ojuṣe Roberts kan ni lati mojuto o pe wsn tẹle ilana to wa nilẹ.
6) Njẹ Ọgbẹni Trump yoo fun wọn ni ẹri?
O le yàn lati farahan niwaju ile aṣofin fun'ra rẹ, ṣugbọn o ṣeeṣe ko kẹ pe agbẹjọro ileeṣẹ aarẹ, White House, Pat Cipollone ati agbẹjọro Ọgbẹni Trump, Jay Sekulow, ni yoo gba ẹnu rẹ sọrọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Democrats n fẹ ki awọn lọgalọga nileeṣẹ aarẹ o jẹri, to fi mọ Oludamọran eto aabo nigba kan, John Bolton, ati awọn ẹlẹri miran, awọn ọmọ ẹgbẹ Republican le pinnu pe awọn ko fẹ ki igbẹjọ naa o pẹ.
Bakan naa ni ko pọn dandan fun awọn ẹlẹri lati yọju sile aṣofin ki wọn o to jẹri wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
7) Nigba wo ni opin yoo de ba gbogbo eyi?
Ilana iru igbẹjọ yii ni pe awọn sẹnetọ gbọdọ maa joko l'ojoojumọ, ayafi ọjọ Aiku, titi ti wọn yoo fi ṣe ipinnu wọn.
O ṣeeṣe ki igbẹjọ naa o gba ọpọlọpọ ọsẹ.
Awọn Democrats yoo fẹ ẹ ki wọn o pari rẹ titi oṣu Keji, ti imurasilẹ idibo abẹle fun 2020 yoo bẹrẹ, ti wọn yoo ti yan aṣoju wọn ti yoo dije tako Ọgbẹni Trump.
- Ariwo kò jẹ́! A ti sún ìgbẹ́jọ́ Ganduje, Tambuwal àti Ihedioha sí ọ̀la
- Obìnrin tó lówó jùlọ ní Africa 'ja orílẹ̀-èdè rẹ̀, Angola lólè' fi kó ọ̀rọ̀ jọ ni
- Atiku náà kéde àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún ẹ̀ṣọ́ alábòò Amọtẹkun
- Mo kàn fẹ́ fi ọmọ tó sọnù gba owó lọ́wọ́ Sọtitobire ni - Afurasí
- Àwọn ará South-Africa yarí nítorí torí gbọ̀ngàn kọ̀ ìgbéyàwó abo-sábo

















