'Ayé kọ́ ló ṣe mi tí ojú fi fọ́, àmọ́ bí mo ṣe ń fi ojú tó fọ lu gangan, tún "generator" ṣe kò yé mi'

Àkọlé fídíò, Blind but lucrative Mustapha Lateef: Mò ń bá ìyá mi kiri ọkà àti Mọ́í-mọ́í ni mo ṣubù

Irinajo Mustapha Lateef kii ṣe eyi to fi bẹẹ dan amọ ko foju kere ara rẹ rara pẹlu iru iṣẹ to n ẹ to si n pa owo wọle fun un.

Mustapha Lateef ṣalaye fun BBC pe kii ṣe pe oju oun fọ lati kekere amọ sababi lo faa.

Bi oju rẹ ṣe fọ jẹ Kayefi fun un to si ni igba ti wọn gba iya oun nimọran lati gbe oun lọ ile iwosan, ko si owo kankan loun ṣi ṣe wa bi oun ṣe wa.

Mustapha Lateef
Mustapha Lateef

Iya Lateef naa ba BBC yoruba sọrọ pe atijẹ atimu gaan lo jẹ ki oun maa din akara ta tori oun ati ọmọ oun.

"Bayii, o ti di owo mi o si lowo, ka le maa jẹun ka le maa mu gan ni ina ti mo n da yii".

Amọ ninu gbogbo eyi, Lateef n dupẹ pe pẹlu ipo oun, iṣẹ ṣi n wa.