Jápa! Ìdí tí orílẹèdè Canada ṣe fẹ́ gba mílíọ̀nù kan àbọ̀ olùgbé míràn èyí tó leè ṣe ọ́ l'àǹfàní rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Canada jẹ Orilẹede ti o fi aye gba awọn olugbe titun paapa julọ lati rọpo awọn agbalagba ti wọn fi iṣe silẹ.
Bo tilẹ jẹ wipe ko dun mọ gbogbo eniyan ninu pe orilẹ-ede Canada gba ọpọlọpọ awọn olugbe titun kaakiri agbaye.
Ninu oṣu Kọkànlá, ijọba apapọ ni orilẹede Canada kede pe awọn un reti Ọkẹ marundinlọgbọn awọn ẹniyan titun ti apapọ rẹ yóò jẹ millionu kan abọ laarin ọdun mẹta.
Eyi yoo mu kí orilẹede Canada gba awọn arinrinajo ti o pọ julọ lagbaye.
Fun ọpọlọpọ ọdun orilẹede Canada ti n gbiyanju lati gba awọn olugbe titun, ti wọn yio ni ẹtọ lati di olugbe ilu naa ṣugbọn ti wọn o tii gba ẹtọ lati di ọmọ orilẹede naa.
Eyi ni wọn n ṣe lati mu ki awọn olugbe Canada pọ sii ti idagbasoke yoo de ba ẹka ọrọ aje wọn.
Canada gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede mi ni ilẹ okere ni awọn oṣiṣẹ wọn ti darugbo ti ọpọlọpọ wọn ko si bí ọmọ pupọ, eleyii lo faa ti orilẹede naa fi n gba awọn arinrinajo titun miran.
Orilẹede Amẹrika ati ile Gẹẹsi ni ida mẹrinla aṣikiri titun ninu ida Ọgọrun awọn olugbe ibẹ.
Mandeleine Sumption ẹni ti o jẹ oludari ni Faṣiti Oxford ni orilẹede Canada ni ọpọlọpọ ile ti o si fẹẹ ju ọpọlọpọ orilẹede lọ ni agbaye. Iyatọ to wa laarin eto igbani wọle ni orilẹede Canada ni wi pe, orilẹede naa fẹran lati gba awọn to ni iṣe ọwọ, nitori wipe ida Ọgọta awọn olugbe Canada lọ wa nibẹ nitori wọn ni ise ọwọ. Nigbati orilẹ-ede Amẹrika ati orilẹede New Zealand, Australia ni osuwọn àti gbedeke ti wọn fin n gba awọn arinrinajo, ti orilẹede Canada ko ri bẹẹ, nitori ko di igba ti ẹniyan bá to ni alatilẹyin ko to le wọ orilẹede naa.















