Ẹ̀yin tẹ ń ṣe’yèméjì, ẹ pinú, ẹ gba PVC yín kẹ́ẹ lòó fún mi – Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Oludije si ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bola Ahmed Tinubu ti ke si awọn ọmọ Naijirira ti ko tii ṣe ipinu lati ṣatilẹyin fun oun lori ipo to n lọ fun.
Tinubu sọ ọrọ̀ yiii lasiko ti akọroyin ileeṣẹ Channels ni United Kingdom fi n fi ọrọ waa lẹnuwo lasiko to lọ si Chattham , United Kingdom.
O ni “mo fẹ kan wọn loju mo si n rọ wọn ki wọn lọ gba kaadi idibo wọn... Mi o polongo ibo fun ẹnikẹni ju ara mi ati ẹgbẹ oṣelu mi lọ... Bi ẹ ko ba tii gba kaadi idibo yin, ẹdakun ẹ lọ gba a.”
Tinubu ni bi oun ṣe fẹẹ niyẹn ati pe ẹnikẹni ti ko ba tii pinu ninu kan rẹ ko dabọ ko tete ṣe bẹẹ.
Tinubu sọ ọrọ yii lẹyin ọrọ to sọ ni Chattam House nibi to ti sọrọ lẹkunrẹrẹ pẹlu awọn ọmọ Naijiria nipa awọn eto to ni fun Naijiria bi o ba jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ Naijiria lọdun to n bọ.
Ọkan gboogi lara nnkan to sọ nibẹ da lori eto ẹkọ to si ni oun yoo gba awọn olukọni sii ti oun yoo si tun ṣe agbekalẹ eto ẹyawo fawọn ọmọ ile ẹkọ.
"Ijọba mii yoo jẹ "ọrẹ-ọdọ"
“Ẹka eto ẹkọ Naijiria nilo ayipada. A o ṣe atunṣe pẹlu amulo ọgbọn ori to jẹ pe ko ni yọ ẹnikẹni silẹ.” Tinubu sọ bẹẹ.
“Eto ẹyawo ikẹkọ yoo wa fun gbogbo awọn to ba fẹ kawe. A o ṣe atunṣe eto Almajiri, bakan naa la o tun kọ ile ẹkọ sii, gba awọn olukọni, a o si ṣe idanilẹkọ fun wọn.”
Lafikun, Tinubu ṣe ileri pe oun yoo ṣe ijọba oun ni ọrẹ-ọ̀dọ̀ ti ko si ni foju kere ẹnikẹni.
“Awọn ọdọ ni ogun ibi ọjọ ọla wa to dara ju, koda wọn le mu agbega ba ẹwa ede ni ilana imọ ẹrọ ko si di ti igbalode lati ran ijọba lọwọ.”














