Wo àmójútó tí o gbọ́dọ̀ fún nkan ọmọkùnrin rẹ láti dènà ààrùn

Yoruba bọ̀, wọn ni imọtoto, lo le ṣẹgun aarun gbogbo.
Eyi to tumọ si pe o ṣe pataki fun gbogbo eeyan, boya ọkunrin tabi obinrin, lati maa ṣe imọtoto ara wọn.
Bo ṣe ṣe koko fun obinrin lati maa ṣamojuto oju ara rẹ, naa lo ṣe pataki fun ọkunrin.
Nitori naa, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo diẹ lara ọna ti ọkunrin le gba mojuto nkan ọmọkunrin rẹ, lati dena aarun.
Diẹ lara nkan ti awọn onimọ nipa ara sọ ree:
Awọn ọna ti o le gba ṣe imọtoto nkan ọmọkunrin rẹ
- Fọ nkan ọmọkunrin rẹ pẹlu omi, to ba ṣee ṣe, pẹlu omi to lọ wọọrọ lojoojumọ lasiko ti o ba n wẹ̀.
- Iwọ ti wọn ko ba dá abẹ fun, rọra fa awọ naa, ki o si fọ abẹ rẹ daadaa.
- Ti o ko ba fọ abẹ awọ naa, omi kan ti wọn n pe ni Smegma ṣee ṣe ko re jọ si ibẹ.
- Smegma ni bii omi tabi ororo, to ma n mu ki ara nkan ọmọkunrin tutu. Ori nkan ọmọkunrin lo ma n wa, ati ni abẹ awọ ti wọn ko ge.
- Ti omi smegma yi ba ro jọ si abẹ nkan ọmọkunrin rẹ fun igba pipẹ, oorun ti ko dara yoo maa jade nibẹ. Bakan naa ni o le fa irora ni ara awọ to bo nkan ọmọkunrin, o si tun le gba kokoro aifojuri mọra.
- O le mu ki ori nkan ọmọkunrin rẹ ko pọ́n tabi ko wú – aarun yii ni wọn n pe ni balanitis.
Bi o ṣe le dena egbò lori nkan ọmọkunrin rẹ
Fifi ọsẹ tabi awọn ọṣẹ olomi igbalode (shower gel) fọ nkan ọmọkunrin rẹ ju bi o ṣe yẹ, le fa ọgbẹ.
Fifi omi to lọ wọọrọ fọ, ni ẹẹkan lojumọ, ki o si fi aṣọ nu u ko gbẹ, ti to lati dena aarun.
Ti o ba fẹ lo ọṣẹ, rii daju pe ọṣẹ ti ko ni kẹmika to le, ko si jẹ ọsẹ ti ko ni òórùn, lati dena ki nkan ọmọkunrin maa yun ọ.
Ma ṣe lo atike tabi lọfinda si nnkan ọmọkunrin rẹ - o le mu ki o maa yun ọ tabi bó.
Yatọ si awọn nkan ti a mẹnuba yii, o ṣe koko fun ọkunrin lati maa ṣe imọtoto abẹ nkan ọmọkunrin ati ẹpọ̀n rẹ.
Ti òógùn ba darapọ mọ irun abẹ, oorun buruku ni yoo maa jade nibẹ.
Nitori naa ni o ṣe nilo fífọ̀ ni oore-koore, paapaa nitori pe àwọ̀tẹ́lẹ̀ (boxers) ma n bo wọn lati aarọ di alẹ.
Lakotan, lọ si ọdọ dokita rẹ ti o ba ṣakiyesi kókó tabi pe nkankan wú sinu nkan ọmọkunrin rẹ.
Orisun - NHS












