Àwọn afurasí agbébọn dáná sun bàbá ẹni ọdún 90 ní Billiri

aworan

Oríṣun àwòrán, Ismailauba/facebook

Arakunrin kan ti o jẹ ẹni ọdun 90 ni awọn agbebon sọ ina si ile rẹ ti wọn si tun fi ada pa ẹeyan meji miran ni igbati wọn ṣe ikọlu si agbegbe Amtawalam ati Pobawure ni ijọba ibilẹ Billiri ni ipinlẹ Gombe. Nigba ti o n sọrọ lasiko to ṣe abẹwo si awọn ibiti iṣẹlẹ naa ti waye, Gomina Muhammadu Yahaya bu ẹnu atẹ lu ipaniyan ati iparun awọn nkan bii ounjẹ to waye naa. Yahaya ṣapejuwe awọn ikọlu naa gẹgẹ bi eyi ti ko ba ojumu ti o le faa rudurudu to si ni ijọba oun ko faramọ.

aworan

Oríṣun àwòrán, Ismailuba/facebook

Yahaya ni ohun ti paṣẹ fun idasile ile-iṣẹ ọlọpa lẹsẹkẹsẹ ni agbegbe naa, to si rọ awọn olugbe ilu ọhun lati kopa ninu didaabo bo ara wọn.

Komisana ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinle Gombe Oqua Etim, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn janduku naa wa lati ba awọn ere oko wọn jẹ ni nitori wọn ko ji ohunkohun. Etim ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣa gbogbo agbara rẹ lati rii wi pe awọn to jẹbi foju ba idajọ ti awọn yoo si ri wi pe alafia pada si awọn agbegbe ti ikọlu naa ti waye.