Agbébọn jí gbogbo mọ́lẹ̀bí aṣòfin kan gbé ní ìpínlẹ̀ Zamfara

Aminu Ardo

Oríṣun àwòrán, Aminu Ardo

Awọn afurasi agbebọn kan ti ji gbogbo mọlẹbi aṣofin kan gbe nipinlẹ Zamfara lọjọbọ.

Aṣofin naa, Aminu Yusuf Ardo ni awọn agbebọn ṣe ikọlu si abule rẹ to wa niluu Jangbebe.

Awọn oṣojumikoro sọ pe awọn agbebọn naa balẹ si abule ọhun ni oru, ti wọn si palẹmọ iyawo ati awọn ọmọ rẹ mẹrin lasiko ti ko si ni ile.

Aminu Yusuf Ardo lo n soju ẹkun guusu ijọba Talata-Mafara ni ile aṣofin ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan agbegbe naa sọ, eeyan mẹjọ mii ni awọn agbebọn naa jigbe tun ji gbe, ti pupọ wọn si jẹ mọlẹbi aṣofin naa.

Ọkunrin ti baba rẹ wa lara awọn ti wọn jigbe sọ fun BBC pe ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn eeyan kan wa ki awọn lori iṣẹlẹ naa.

O ni titi di asiko ti oun n ba ileeṣẹ BBC sọrọ, awọn ajinigbe naa ko ti bere owo lọwọ itusilẹ kankan lọwọ awọn.

Kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Zamfara, Ibrahim Magaji Dosara fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ sugbọn o ni iwadi si n lọ lọwọ lori ikọlu naa.