Wọ̀n ní ka pàrọmọ Saraki lórí ìdigunjalè Offa - Ẹlẹ́rìí

Oríṣun àwòrán, Others
Shamsudeen Bada, ọkan lara awọn ẹlẹrii ati afurasi to n jẹjọ niwaju ileẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti sọrọ bi ẹka ileesẹ ọlọpaa to n koju ijinigbe ni Naijiria, IRT, eyi ti Abba Kyari le waju rẹ ni ṣe ni ki awọn parọ lori idigunjale to waye niluu Offa lọdun 2018.
O ni awọn ọlọpaa sọ fun oun pẹlu awọn yooku oun lati parọmọ gomina ana nipinlẹ Kwara, Bukola Saraki, pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ idigunjale to waye ni ọjọ karun un oṣu kẹrin ọdun 2018.
Pẹlu ẹri eyi ti agbẹjọrọ rẹ, Mathians Emeribe, mu wa si ileẹjọ, Bada ẹni to jẹ igbakeji alaga tẹlẹ fun ijọba ibilẹ Irepodun nipinlẹ Kwara, ni oju oun ri ọpọlọpọ nigba ti awọn ko si awọn ahamọ awọn ọlọpaa.
Awọn afurasi marun-un to n jẹjọ lori idigunjale naa ni - Ayoade Akinnibosun, Ibikunle Ogunleye, Adeola Abraham ati meji miiran ni ileeṣẹ ọlọpaa wọ wa si ileẹjọ pe wọn lẹdi apopọ lati ja ile ifowopamọ kan lolẹ, ti wọn si sekupa ọlọpaa mẹsan-an ati awọn araalu.
Awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi naa ni ẹsun ipaniyan, ole jija ati awọn ẹsun miiran.
Bada ni nigba ti awọn mọlẹbi awọn afurasi to wa ni ahamọ ni awọn yoo gbe ọlọpaa lọ si ile ẹjọ, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa IRT sọ fun wọn pe awọn gba asẹ lati ọwọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, ati pe ko si ileẹjọ nipinlẹ Kwara to le da awọn duro isẹ awọn ni siṣe.
O tẹsiwaju pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa IRT ni awọn yoo fi wọn silẹ ti wọn ba le darukọ Saraki gẹgẹ bi ẹni to jẹ agbatẹru wọn.
"IRT yinbọn fun Ayo Akinnibosun lẹsẹ nigba to ni oun ko le parọmọ Saraki.
"Nigba ti yinbọn lu, aarẹ bẹrẹ si ni mu mi, DCP Abba Kyari mu awọn nọọsi kan wa lati wa tọju mi. Ki wọn to tumi silẹ , ileeṣẹ ọlọpaa ẹka IRT sọ fun pe n ko gbọdọ ba ẹnikẹni sọrọ lori iṣẹlẹ to waye."
"Wọn ni n ko gbọdọ lọ si ileẹjọ ati pe mo ni lati fi oṣelu silẹ."
Adajọ Halimat Salman ti wa sun igbẹjọ ọhun si ọjọ kẹrindinlogun, kẹtadinlogun ati ọjọ kejidinlogun ọdun 2023.















