Ẹ yé fi fóònù lé mi kiri lórí ọ̀rọ̀ tí mo sọ lórí ìbálòpọ̀- Toyo-Baby

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajúgbajà òṣèré, Olayode Juliana tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Toyo baby ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn tó ń bu ẹnu àtẹ́ lù ú lórí ìpinu rẹ̀ láti má nì í ìbálòpọ̀ títí òun fi máa ṣe ìgbéyàwó.
Lọ́jọ́ Àìkú ni Juliana ti kọ́kọ́ fi fídíò kan síta níbi tó ti sọ̀rọ̀ nípa ìpèníjà tó ń la kọjá nítorí ìpinu rẹ̀ láti wà ní mímọ́ títí dí àsìkò tí òun yóò ṣe ìgbéyàwó.
Nínú fídíò náà ni Juliana ti sọ àwọn nǹkan tó ń là kọjá lórí ìpinnu yìí pàápàá lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Kí ní Juliana sọ nínú fídíò ọ̀hún?
Nínú fídíò kan tí Olayode Juliana fi sojú òpó Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹfà oṣù Kejìlá ọdún 2022 ló ti sọ wí pé ọ̀rọ̀ ara òun kò fẹ́ yé òun mọ́.
Juliana ní gbogbo bí ó ṣe ń ṣe òun ni pé kí òun ní ìbálòpọ̀, òun tó jẹ́ wí pé òun ti pinnu wí pé tí kò bá di alẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó òun kò ní dan irú rẹ̀ láṣà.
Ó ní gbogbo ìpèníjà tí àwón ènìyàn tí wọ́n ṣe irú ìpinnu yìí ń là kójá ni òun náà ń là kọjá nítorí náà kí wọ́n má jẹ̀ ẹ́ kí ìgbádùn ìṣẹ́jú mélòó kan ba ìpinnu wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.
Ó fi kun pé nígbà tí ara òun kò fẹ́ gbà á mọ́ ni òun kọjú sí Ọlọ́run láti bá a sọ̀rọ̀.
Juliana ní òun sọ fún Ọlọ́run wí pé ṣe ó sọ nínú ìwé mímọ́ Pọ́ọ̀lù pé bí ènìyàn kò bá le mú ara dúró mọ́ ònítọ̀hún le ṣe ìgbéyàwó, bóyá kí òun lọ torí ìbálòpọ̀ ṣe ìgbéyàwó.
Fídíò yìí ti wá ń fa onírúurú àríwísí láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, bí àwọn ènìyàn kan ṣe ń kan sárá sí òṣèrébìnrin náà lórí ìpinnu rẹ̀ ni àwọn mìíràn ń yọ ẹnu gẹ̀rẹ̀ sí.
Àwọn mìíràn tilẹ̀ ń sọ pé àìní ìbálòpọ̀ ṣaájú ìgbéyàwó kò túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ̀ yóò balẹ̀ tó bá ṣe ìgbéyàwó tán àti pé kò túmọ̀ sí pé yóò ní ìgbéyàwó aláyọ̀.

Oríṣun àwòrán, Olayode Juliana/Instagram
Ẹ yé fi fóònù lé mi kiri, mi ò kábàámọ̀ fídíò tí mo ṣe
Lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní kàn sí Juliana lórí fídíò tó ṣe ní òṣèrébìnrin náà ti rọ àwọn ènìyàn láti fi òun sílẹ̀.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Toyo Baby fi sójú òpó Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ru ló ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn tó ń pè é láti ba sọ̀rọ̀ lórí fídíò náà.
Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún, Juliana ní òun kò kábàámọ̀ wí pé òun ṣe fídíò náà nítorí òun ṣe fídíò náà láti fi ṣe ìwúrí fún irú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní irú ìpinu tí òun ní láti má jẹ̀ ẹ́ kí ọkàn wọn pamí láti yí ìpinu wọn padà.
Juliana ní láti ìgbà tí òun ti fídíò náà jáde ni gbogbo ènìyàn ti ń pe òun lórí fóònù láti bá òun sọ̀rọ̀ lórí fídíò àti pé ní ṣe ló dàbí wí pé gbogbo ènìyàn ló ti ní nọ́mbà fóònù òun lọ́wọ́.
Ó ní kí àwọn ènìyàn dẹ́kun fífi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí òun lórí fídíò náà nítorí òun kò kábàámọ̀ àti pé àsìkò yìí ni inú òun dùn jù ní ìgbésí ayé òun.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ń rò wí pé nítorí àwọn kò lè ṣe nǹkan, ẹlòmíràn kò ní le ṣe nǹkan náà àti pé òun kò mọ ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń bínú pẹ̀lú àwọn nǹkan tí òun sọ.
Ó tẹ̀síwájú pé jíjáde síta láti sọ ìlàkàkà òun nípa ohun tí òun ń là kọjá lórí wí pé òun kò ní ní ìbálòpọ̀ kò túmọ́ sí wí pé òun kì í ṣe onígbàgbọ́ mọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ni kì í lè sọ irú rẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù òun tí àwọn ènìyàn yóò sọ.

Oríṣun àwòrán, Olayode Juliana/Instagram
Òṣèré náà ní òun ṣe ìpinu òun láti fi sin Ọlọ́run ni tóun sì ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa ran òun lọ́wọ́ láti gbé ìpinu ọ̀hún délẹ̀.
Juliana tún là á mọ́lẹ̀ pé gbígbé ìgbéayé tí mímọ́ kọjá ọ̀rọ̀ ìbálé nìkan, ó ní ó jẹ́ wíwá ní àyíká tí kò ní sí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀, àgbèrè àti àwọn ìwà kòtọ́ mìíràn lórí ìbálòpọ̀.
Bákan náà ló ní kò sí bí àwọn ènìyàn ṣe lè bu ẹnu àtẹ́ lu òun tó òun kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti pé gbogbo èébú náà ló tún kí ọkàn òun tún le si ní.
“Ìhà tí àwọn ènìyàn kọ sí fídíò náà tún jẹ́ kí n tún ṣe ìpinu mi lákọ̀tun pẹ̀lú Ọlọ́run lórí ìbálòpọ̀.”












