Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni gbogbo nkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí a wà ní ààfin - Prince Harry

Oríṣun àwòrán, Netflix
Ọmọọba Harry ti sọ̀rọ̀ lori awọn iṣẹlẹ to mu ki oun ati iyawo rẹ, Meghan, kuro ni aafin.
Ninu fidio kan ti wọn fi polongo fiimu tọkọtaya naa ti yoo jade sori amohunmaworan ori ayelujara Netflix, ni Harry ti sọrọ yii.
O salaye pe irora ati ìyà ni àwọn obìnrin to jẹ iyawo nile ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì n dojú kọ - paapaa iya rẹ, Diana, ati iyawo rẹ, Meghan.
Idẹyẹsi nitori ẹ̀yà ti Meghan jẹ, tun wa lara nkan ti wọn sọ̀rọ̀ le lori.
Ọjọbọ ni fiimu naa yoo bẹ̀rẹ̀ - abala mẹ́fà ni wọn pin si.
Ninu fiimu naa ni tọkọtaya ti sọ orisirisi ọrọ, eyi to fihan pe wọn o ṣe tán lati pari ija pẹlu awọn ara ile ọba.
Dipo bẹẹ, wọn tun fi ẹ̀sùn kàn pe, wọn gbógun ti Meghan, nitori itẹlọrun àwọn kan.

Oríṣun àwòrán, Netflix
Ọṣẹ to kọja ni awuyewuye ti n waye lori fiimu naa, lẹyin ti wọn lo aworan Catherine, Princess of Wales, ati fidio ipolongo tuntun yii, to ni aworan rẹ, ati ti Camilia, ayaba King Charles, ati ti Sophie, Countess of Wessex.
Fidio ipolongo naa safihan bi tọkọtaya naa ṣe sọ bi ibasepọ wọn ko ṣe dán mọ́rán pẹlu awọn ara ile ọba, awọn akọroyin ati awọn araalu - eyi to mu ki Ọmọọba Harry ati Meghan kó lọ si America.
Fidio ìpolongo naa safiwe iriri ti Princess Diana ati Meghan ní.
Harry sọ pe gbogbo otitọ nipa rẹ ni awọn mọ.
Ile ọba ko tii sọ ohunkóhun nipa fidio yii, sugbọn ireti wa pe awuyewuye yoo waye lori awọn ẹ̀sùn ti wọn fi kan wọn ninu fiimu wọn.
"Fíìmù yii yoo tu asiri àwọn nkan to sẹlẹ ni kọlọfin, eyi to mu ki a fi ipo wa silẹ lọdun 2020.
Àwọn oluworan yoo si tun ma a reti lati mọ boya wọn o sọrọ nipa ọrọ ti wọn sọ fun Oprah Winfrey, ninu ifọrọwanilẹnuwo.
Meghan sọ pe ẹnikẹni ko ṣe atilẹyin fun oun ninu idile ọba, bẹẹni wọn tun dẹyẹ si.








