Iléẹjọ́ ní kí wọ̀n yẹgi fún ọkùnrin kan fẹ́sùn ìfapábánilòpọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileẹjọ giga ipinlẹ Edo to wa ni ilu Auchi ti ni ki wọn lọ yẹ igi fun ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Taofeek Isah fẹsun ifipabanilopọ.

Bakan naa ni ileẹjọ tun ran awọn meji to jẹ ọrẹ rẹ lo si ẹwọn ọlọdun gbọọrọ ṣugbọn ti ọkan ninu awọn afurasi ọhun, Godwin Adeyemi, moribọ bi adajọ ṣe ni ki o maa lọ sile rẹ layọ ati alafia.

Lara ẹsun marun-un ti awọn ka si wọn lọrun ni ifipanilopọ, ifiyajẹni lọna ait , ijinigbe ati awọn ẹsun miiran.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Onidajọ Philip Imoedemhe, ninu idajọ rẹ lọjọbọ ọsẹ yii ni ki wọn yẹ igi fun afurasi akọkọ, ki afurasi keji lọ si ẹwọn ọdun mẹrin, afurasi kẹrin lọ si ọdun mọkandilogun.

Adajọ Imoedemhe ni oun gbe idajọ naa kalẹ lori awọn ẹri ti wọn gbe wa si ileẹjọ, to si fi mulẹ pe awọn afurasi naa jẹbi ẹsun ti fi wọn fi kan wọn.

"Pẹlu awọn ẹri to wa niwaju, ileẹjọ ileejọ palasẹ pe ki wọn yẹ gi fun Isah, ki awọn yooku si lọ maa gba atẹgun ni ọgba ẹwọn."

Agbẹjọro ijọba, Clement Eseigbe ni Isah pẹlu awọn ọrẹ mẹta gbinmọ lati fipa ba ọmọ ogun odun kan ti orukọ rẹ n jẹ Blessing sun.

O ni awọn afurasi naa ṣe isẹ laabi naa ni ọjọ kejilelogun ọdun 2021 ni agbegbe Okpelle ni ijọba ibilẹ Etsako nipinlẹ Edo.

"Awọn afurasi fi ata ra oju ara ọmọbinrin naa eyi to ṣe ijamba fun, ti wọn si tun fi ada naa."

Ninu iroyin miiran, ileẹjọ tun ran baba ẹni ọdun mọkanlelọgọta ọdun, Taiwo Buoro lọ si ẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun ifipanilọpọ ọmọ ọdun mejila.

Buoro, ẹni to jẹ agbẹ ṣe ẹsun naa ni ọjọ kan kọkandinlogun ni agbegbe Ososo ni ijọba ibilẹ Akoko Edo