Mi ò rò wí pé mà á tẹ̀síwájú láti máa gbá bọ́ọ̀lù fún Brazil - Neymar

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ògbóǹtarigì eléré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Brazil, Neymar da Silva Santos ti ní òun kò rò wí pé òun yóò tẹ̀síwájú láti má gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀ èdè Brazil mọ́.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí orílẹ̀ èdè náà ṣe pàdánù ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ipele "quarter final" tó wáyé láàárín wọn àti orílẹ̀ èdè Croatia nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́.

Lọ́jọ́ Ẹtì ni Brazil àti Croatia gbo ewúro síra wọn lójú àmọ́ tí Brazil lulẹ̀ nínú ìdíje náà.

Neymar ní òun yóò fara balẹ̀ láti ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí òun tó ṣe ìpinnu kan ní pàtó nítorí bí ọ̀rọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Brazil ṣe ń lọ kò yé òun mọ́.

"Kì í ṣe wí pé mo ti pinnu wí pé mi ò ní gbá bọ́ọ̀lù fún Brazil mọ́ àmọ́ mi ò sọ wí pé màá tún gbá fún wọn mọ́."

"Mo fẹ́ fara balẹ̀ láti rò ó dáadáa, kí n mọ ohun tó tọ́ fún mi àti èyí tí yóò ṣe ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Brazil ní àǹfàní kí n tó ṣe ìpinnu kankan."

Neymar ní bí àwọn ṣe pàdánù ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà sọ́wọ́ Croatia dun òun ju ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí àwọn pàdánù sọ́wọ́ Belgium níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́dún 2018.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dùn òun pé àwọn pàdánù ìdíje yìí, òun kan sáárá sí àwọn akẹgbẹ́ òun fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe.

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Brazil, Tite kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ẹ̀wẹ̀, akọ́nimọ̀ọ́gbá Brazil, Adé or Leonardo Bacchi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Tite tí kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ ní tirẹ̀ lẹ́yìn tí Croatia díyà jẹ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀.

Tite ní àsìkò ti tó fún òun báyìí láti fipò òun sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tó ti ń tukọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Brazil.

Ó ní ohun ìbànújẹ́ ló jẹ́ fún òun bí Croatia ṣe na àwọn àti pé àsìkò ti tó fún òun láti máa lọ.

Ní ọdún 2016 ni Tite gba àkóso akọ́nimọ̀ọ́gbá Brazil to sì gba ife ẹ̀yẹ Copa America lọ́dún 2019.

Ìdíje mọ́kànlélgọ́dọ́ta nínú mọ́kànlélọ́gọ́rin ni Tite gbà fún Brazil gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá.