'Oṣù márùn-ún ni mo fi kọ́ "Power Bike" gígùn torí ìbẹ̀rù àmọ́ kò síbi tí mì ò lè gùn ún wọ̀ lónìí'

Àkọlé fídíò, Omolewa Adesuyi lady biker: Mò lè gun Ọ̀kadà mi dé ibikíbi tí ọ̀nà bá ti dé ibẹ̀
'Oṣù márùn-ún ni mo fi kọ́ "Power Bike" gígùn torí ìbẹ̀rù àmọ́ kò síbi tí mì ò lè gùn ún wọ̀ lónìí'

“Mo fẹ́ẹ̀ ṣubú lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ gùn ún jáde bí ọ̀gá"

Ọpọlọpọ lo maa n sọ pe ọkunrin lo maa n gun kẹkẹ amọ Omolewa jẹwọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pe irọ nla ni.

“Ohun ti ọkunrin le ṣe, obinrin naa le ṣe e”, eyi ni igoya ti Omolewa ni to ṣe ti gun ọkada rẹ lọ kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria bii Benin, Ilorin, Kogi, Ekiti, Ogun, Abuja ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Omolewa

“Bi mo ṣe bẹrẹ ni pe mo ni awọn ọrẹ to maa n gun ọkada kaakiri ipinlẹ ti wọn si maa n gbe mi dani lẹyin wọn”.

Omolewa ni oun fẹran ọkada gigun toripe ẹni to wa lori ọkada yoo le ri ohun gbogbo to wa layika rẹ daadaa.