Emir Kano tuntun ti balẹ̀ sí ìlú Ilorin fún àyẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́ta

Emir

Emir tuntun ipinlẹ Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero ti gunlẹ si ilu Ilorin fun abẹwo ọlọjọ mẹta.

Nnkan bi aago meji ọsan Ọjọbo ni ọkọ ofurufu to gbe e balẹ bagẹ si papakọ ofurufu ilu Ilorin.

Emir naa ti iya rẹ jẹ ọmọ bibi ilu Ilorin lo gori alefa lẹyin ti gomina ipinlẹ Kano, Ibrahim Ganduje yọ Emir ana to tun jẹ gomina banki apoapọ Naijiria tẹlẹ, Alhaji Lamido Sanusi nipo.

Kẹkẹ ẹlẹṣin ni Emir ọhun yoo gun de Aafin ọba Ilorin.

Ogunlọgọ awọn eeyan ilu Ilorin lo peju si papakọ ofurufu ilu Ilorin lati ki Emir ọhun kaabọ si ilu iya rẹ.

Emir
Àkọlé àwòrán, idunu atayọ lawọn eeyan naa fi ki Emir kaabọ

Emir ilu Ilorin ati awọn eeyan ti duro de ọlọla ọba Kano, ti eero si n tu kẹti kẹti lati wa ki ọba naa kaabọ.

Ilorin
Àkọlé àwòrán, Ẹsẹ ko gbero ni papakọ ofurufu ilu Ilorin.

Awọn olorin ibilẹ atawọn oloye ilu miran miran ko gbẹyin nibẹ pẹlu.

Iya Emir ọhun ni ọmọ ọba iIlorin to fẹ Ado Bayero to doloogbe ni Kano.

Pataki àbẹwò yi ni pe ọmọ ọmọ ọba ikejo ní Emir Kano jẹ.

Emir Bawa lo bi iya rẹ ti o si lọ fẹ ọba Kano Ado Bayero