Third mainland bridge: Afárá Third mainland gùn, ṣùgbọ́n afárá Hong Kong-Zhuhai tó gùn jùú lọ ti di ṣíṣí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si aniani pe afara Third mainland bridge ni afara ori omi to gun julọ ni ilẹ Olooru Afirika.
Gbogbo akitiyan lati kọ omiran lẹyin rẹ ni ko si tii ri oju ọjọ rere.
Bayii, ijọba Naijiria ti kede lati tun afara Third Mainland ṣe bẹrẹ lati oni, ọjọ kẹrinleogun, oṣu keje Wo àwọn ọ̀nà míràn tí o leè gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti afára Third Mainland
Amọṣa o, lorilẹ-ede China wọn ti ṣi afara ti yoo jẹ akẹyinde gb'ẹgbọn fun afara Third mainland bridge.
Orukọ afara naa ni afara Hong Kong-Zhuhai, ohun si ni afara to gun julọ ti wọn kọ si ori okun.
Aarẹ orilẹ-ede China, Xi Jinpin ṣi afara naa ni ọjọ Iṣẹgun lẹyin ọdun mẹsan an ti wọn bẹrẹ kikọ rẹ.
Kilomita marundinlọgọta ni gigun rẹ, Ogun biliọnu dọla $20b ni wọn si fi kọọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi awọn to wa nidi kikọ rẹ ṣe sọ, oṣiṣẹ mejidinlogun lo padanu ẹmi wọn sori kikọ afara naa.
Ọjọru ni wọn ṣi afara naa fun lilọ-bibọ ọkọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kini awọn ohun aramanda to rọ mọ afara yii?
Afara naa so awọn ilu nla mẹta to wa letido ni gusu orilẹede China pọ-Hong Kong, Macau ati Zhuhai.
Ko si ilẹ riri, iji lile tabi ikun omi to lee bi afara naa wo.
Kini awọn eeyan n sọ lori afara yii?
Amọṣa, oniruru ariwisi lo ti waye lori afara olowo iyebiye naa, paapaa julọ lori idaboobo ayika.
Yatọ si awọn eeyan to ku, ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ miran ni wọn tun ti di alabọ ara tabi fi ara ṣeṣe lasiko kikọ afara naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa lawọn ẹgbẹ ajafẹtọ ayika naa tun ti n pariwo sita pe wahala ti kikọ afara naa ti ko ba awọn ohun abẹmi ti wọn n gbe ninu okun naa ko kere.
Awọn ẹgbẹ naa ni awọn aramanda ẹja agia (Dolphins) to wa ninu rẹ lo tin dinku lati mejidinlaadọjọ si mẹtadinlaadọta pere.
- Èmi Ọba tí wọ́n ń kó jẹ nígboro- Oluwo ti ilú Iwo
- Nǹkan mẹ́sàn án tí Mùsùlùmí gbọdọ̀ ṣe nínú oṣù Dhual- Hijjah
- Wo bí ètò ìsìnkú Tolulope Arotile ṣe lọ nílùú Abuja
- Donald Trump ti gbà pé Coronavirus yóò burú jáì kí ǹkan tó dára fún Amẹ́ríkà
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Hushpuppi ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n l'America? Ẹ wo àbájáde ìwádìí wa














