Highlighlight of Liverpool vs Chelsea: Liverpool pègúnrẹ́, wọ́n gbé ife ẹ̀yẹ̀ Premier league lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún

Salah atawọn agbabọọlu Liverpool gbe ife ẹyẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igba akọkọ rèé ti wọn ti n duro de ife yii ko tẹ wọn lọwọ lati igba ti Premier league ti bẹrẹ.

Balogun ikọ agbabọọlu Liverpool, Jordan Henderson gbe ife ẹyẹ Liigi ilẹ Gẹẹsi lalẹ Ọjọru ni papa iṣere Anfield.

Eyi ni igba akọkọ ti Liverpool yoo gba ife ẹyẹ naa laarin ọgbọn ọdun bayii.

Henderson tẹwọ gba ife ẹyẹ naa lọwọ ọkan lara awọn eekan agbabọọlu Liverpool, Kenny Daglish to jẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa nigba ti wọn gba ifẹ ẹyẹ naa kẹyin lọdun 1990.

Awọn agbabọọlu Liverpool gbe ife ẹyẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹfa ni o ti fidimulẹ pe Liverpool ni olubori liigi Premiership ti ilẹ Gẹẹsi lọdun yii nigba ti o si ku ifẹsẹwọnsẹ meje ki saa liigi tọtẹ yii pari.

Àkọlé fídíò, Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran

Lọjọ naa ni Manchester City to sun mọ wọn julọ lori atẹ igbelewọn liigi premiership ilẹ Gẹẹsi lọ fidirẹmi ni ile Chelsea lọjọ naa lọhun.

Nitori ajakalẹ arun coronavirus, ko si ẹyọ horo ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa kankan ni papa iṣire naa gẹgẹ bi o ti ṣe maa n ri.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....