Emezana Purity: Kí ló mú òjòwú ọ̀rẹ́kùnrin fì ìbínú yìnbọn lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lẹ́yìn tó lóun kò ṣe mọ́

Emezana Purity

"Ọlọrun lo ni maa wa laye loni" ni ọrọ to n jade lẹnu arabinrin Emezana Purity nigba to n ṣalaye bi ojowu ọrẹkunrin rẹ ti ṣe binu yinbọn lu.

Ọrẹkunrin rẹ ti wọn ko fẹ ara mọ James Eno, lo yinbọn lu Emezana nile rẹ to wa ni Warri ni ipinlẹ Delta.

Iroyin Purity gba oju opo ayelujara kan, ti ọpọ eeyan si n ran ọrọ ẹni ọdun mẹrinlelogun yi lẹnu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Delta ti wa fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC, ti wọn si ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Purity tẹnu bọrọ fun BBC nileewosan to ti n jẹ irora lati ipasẹ ibọn yinyin naa, to si ṣalaye bi Eno ṣe wa ba oun nile, to fa ibọn yọ lẹyin toun sọ pe oun ko ṣe mọ.

"Ọrọ kan wa laarin wa ti mo si pada ri ododo rẹ. Bi mo ṣe ni mi o ṣe mọ fun, pe ka yẹra diẹ fun ara wa. Mi o sọ fun pato pe mi o ṣe mọ''

Àkọlé fídíò, Kò tíì tó oṣù kan tí èmí àti Favour bẹ̀rẹ̀ sí ni fẹ́ ara wa tí mo pa á ṣe ògùn owó

Purity sọ pe James fẹsun kan oun pe oun n fẹ alabaṣiṣẹ rẹ nibi toun ti n ṣowo. O sọ pe alabagbe kan ni oun ati ẹni naa.

"Ko gba mi gbọ tori naa mo ba pinnu pe ka maa lọ lọtọọtọ lati fi koore anbili''

Bi Purity ti ṣọ fun pe Eno pe ko ṣe mọ, bẹẹ ni ọkunrin naa fa ibinu yọ, to si ni ki obinrin naa ko owo ti oun fi da ni okoowo pada.

''Bo ti ṣe n fibinu sọrọ ni Mama mi ba gba mi nimọran pe o le ṣe mi ijamba''

Nitori naa lawọn mọlẹbi mi ba fi ni ko fun awọn lasiko diẹ lati san owo naa pada. O ni ko buru.

Amọ ko ṣe suuru di igba naa

" Dokita ni iyalẹnu lo jẹpe mo ye iṣẹlẹ ibọn yinyin naa''

Purity wa tẹsiwaju lati salaye bi ọrẹkunrin rẹ ṣe ṣadede yọ si lati gbẹmi rẹ.

"O yọ ibọn jade to fẹ yin mọ mi. Bi mo ṣe na ọwọ mi soke ni yẹn''

.

Oríṣun àwòrán, Emezana Purity/Facebook

O ni ọta ibọn naa gba ọwọ oun jade to si wọ inu aya rẹ lọ ko to pada jade lẹyin rẹ.

"Ori lo yọ mi pe ọta ibọn naa ko wọ inu ọkan mi lọ ṣugbọn o fọ egungun aya mi mẹta''

Purity fi kun pe, ọkan ninu egungun aya to fọ naa ya ẹdọ fooro rẹ tori naa wọn ni lati yara ṣe iṣẹ abẹ fun oun.

O ni lati igbati wọn ti ṣe iṣẹ abẹ yii tan, a ti mi daada ti di iṣoro fun oun.

"Bi mo ba mi yoo dabi pe wọn fi nkan gun mi laya''

Awọn Dokita sọ pe iyalẹnu lo jẹ pe Purity si wa laye lẹyin ibọn yinyin naa.

Ọjọ mẹrin gbako ni Purity fi n gba afẹfẹ oxygen nitori ko le da nikan mi fun ara rẹ .

Àkọlé fídíò, Mesach Oyediran: Ọba ni Dafidi tó ń lu dùùrù, tó sì kọ sáàmù, ta ni èmi tí kò ní le yin

Inu fufu:

Nigba ti wọn ṣi n fẹ ara wọn, Purity ni oun ri apẹrẹ pe ọrẹkunrin oun a maa yara binu pupọ.

"Mo ti maa n gbọ pe iru nkan bayi n ṣẹlẹ koda mo ri loju opo ayelujara amọ mi o lero pe o le ṣẹlẹ simi''

O ni bi ọta naa ti ṣe ba oun, loun ba sare wọle toun si dibọn bi igba pe oun ti ku.

Ina ọba lọ nigba naa ti eyi si mu ki ariwo ẹrọ amunawa generator bo iro ibọn naa mọlẹ nigba ti Eno yinbọn mọ.

O ni nigba toun ko gburo rẹ mọ loun ba figbe ta tawọn alabagbe si sare gbe oun lọ si ile iwosan.

Purity ti lo to ọjọ mẹjọ bayi ni ile iwosan ti ireti si wa pe ara rẹ ko ni pẹ ya.