Man kills girlfriend in Edo: Ìyá ọlọ́mọ mẹ́rin kagbako ikú lọ́wọ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ẹni ọdún 23

Oríṣun àwòrán, other
Iwe iroyin abẹle, The Vanguard, jabọ pe opo ni obìnrin naa, Rosemary Ifeoma, lati ilu Orogun nijọba ibilẹ Ughelli nipinlẹ Delta.
Iroyin sọ pe nise ni Adebayo la igi mọ obìnrin naa, to si ba ni ibalopọ lẹyin naa.
Bakan naa ni iroyin sọ pe o tun fi igi lu ọmọ obinrin naa kan to jẹ ọmọ ọdun mẹtala, ko to o ba iya rẹ lopọ̀, nireti pe ọmọkùnrin naa ti ku.
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Kí ni Ọ̀gágunfẹ̀yìntì Buratai ń ṣe ní Benin Republic, ìlú tí Sunday Igboho ti ń jẹ́jọ́?
- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà dá Akeredolu láre lórí ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
- Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha di oṣu kẹ́jọ lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọmọ́débìnrin tọ́rọ̀ kàn lẹ́nuwò
Ẹnikan to n gbe ni adugbo naa to ba awọn akọroyin sọrọ ní "opo ni obìnrin naa to ti bi ọmọ mẹrin, sugbọn abigbẹyin rẹ to jẹ ọmọ ọdún mẹtala nikan lo n gbe pẹlu rẹ.
"O ni ìṣòro owo lati sanwo ile to n gbe, eyi si lo mu ko tọrọ aaye lati ma a sun sinu ile kan ti wọn n kọ lọwọ ni adugbo, titi ti yoo fi ri owo kojọ nibi okoowo rẹ lati gba ile."
Ẹni naa fikun pe gbogbo ara adugbo lo mọ pe obìnrin naa ni ọrẹkunrin kan to jẹ birikila, to ma n wa a wa sinu ile naa.
"Owurọ kutu ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje ni ọmọ obìnrin naa sare wa a sọ fun awọn ara adugbo lẹyin to taji, nipa bi afurasi naa ṣe kọlu oun ati iya rẹ loru mọju."
O ni wọn gbe ọmọ naa lọ sileewosan fun itọju. Lẹyin naa si lo mu wọn lọ si ibi ti ti afurasi naa, Adebayo, ti n sisẹ.
"Bi Adebayo ṣe ri ọmọ naa lọọkan lo bẹrẹ si ni salọ, ko to o di pe ọwọ tẹ ẹ pẹlu iranlọwọ àwọn ọlọpaa."
Afurasi naa sọ fun awọn ọlọpaa pe oun ko fi igi lu iya ati ọmọ lori.
O ni lootọ ni oun wa si ọdọ wọn, sugbọn ede aiyede waye laarin wọn nitori bi obìnrin naa ṣe fẹ ko ba wa simẹnti lati ṣe nkankan.
"O ni ki n jade kuro ninu ile oun, nigba ti ede aiyede bẹrẹ. Mo si jáde, sugbọn mo ṣìnà nigba ti mo n lọ, eyi to mu ki n tun pada sinu ile naa.
"Nigba ti ma a fi de ibẹ, wọn ti ti geeti. Idi niyẹn ti mo fi fo odi ile naa wọle, ti mo si wọ yaara wọn."
Adebayo ni ọmọ obìnrin naa dunkooko lati fi ọ̀bẹ gun oun.
"O wọ inu yaara lọ, o si mu ọ̀bẹ jade. Mo ti i danu, o si fi ori gba ogiri, eyi to mu ko daku."
O ni ibi ti iya ọmọ naa ti n le oun nitori ọmọ rẹ, ti oun si n gbiyanju lati ti i danu, lo ti ṣubú, to si fi ori gbalẹ ti ẹ̀jẹ̀ fi n jade lori rẹ.
O ṣalaye pe oun ko fi igi lu ẹnikẹni lori, tabi ba obinrin naa lo pọ.
Agbenusọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo, Kontongs Bello sọ fun awọn akọroyin pe wọn o gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ, ti iwadii ba ti pari.













