Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàfihàn ọmọ ológun méjì tó lọ́wọ́ nínú ikú Ààfáà kàn nípínlé Yobe

Oríṣun àwòrán, others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Yobe ti sa fihan awọn ọmọ ologun meji ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ṣekupa agbajugbaja aafa, Sheikh Goni Aisami lọjọ Eti ọsẹ to kọja.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Yobe, Dungus Abdulkarim ninu atẹjade kan to n fi ransẹ si awọn akọroyin lo ti kede ọrọ naa.
O ni awọn ọmọ ologun mejeeji, Corporal John Gabriel ATI Corporal Adamu Gideon ni wọn wa lati 241 RECCE Battalion, Nguru ni ipinlẹ Yobe.
AbdulKarim tẹsiwaju pe Alufaa naa ni o rinrinajo lati ipinlẹ Kano, ti o si gbe Corporal John Gabriel, ọkan lara awọn afurasi si ninu ọkọ rẹ,
sugbọn nigba ti wọn de abule Jaji Maji, John Gabriel ni oun ṣe akiyesi pe ariwo kan n waye nibi taya ẹsẹ ọkọ naa, eyin lo mu aafaa duro lati wo nkan to fa ariwo lẹsẹ ọkọ naa.
O ni kete ti Alfaa Goni AISAMI bọ silẹ ni ,John Gabriel sina bolẹ fun, ti o si lọ wọ oku rẹ sinu igbo.

John Gabriel gbinyanju lati gbe ọkọ naa salo sugbọn ọkọ naa kọ lati sisẹ, to o si ransẹ si ẹnikeji Adamu Gideon lori ẹro ibaraẹnisọrọ pe ko sure lati maa bọ.
“Nigba ti alufaa naa bọ silẹ lati inu ọkọ rẹ lati wo ẹsẹ taya rẹ ni ọmọ ologun naa gbe ibọn sita, ti o si sina bolẹ fun. O wọ oku naa lọ sinu igbo.
“Lẹyin naa ni o pada sidi ọkọ sugbọn ọkọ naa ko sisẹ, ti o si ransẹ pe ẹnikẹji rẹ lati ran an lọwọ.
AbdulKarin fi kun pe ẹnikan to kọja lọ lo ri oku naa ati awọn ọmọ ologun lẹgbẹ ọkọ, ti o si to awọn ọlọpaa leti.
O ni kete iroyin naa lo ṣe iranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati tete mu awọn ọmọ ologun naa.
Abdulkarim ni awọn mejeeji ti wa atimole, iwadi si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.















