Àwọn aṣojú ìjọba Oyo kan ń tojú bọ ìlànà yíyan Alaafin Oyo tuntun - Ọmọọba ìdílé Adeitan Atiba pariwo síta

Ọkan lara awọn ọmọ oye fun itẹ Alaafin nilu Ọyọ, Ọmọọba Afọlabi Ademọla Adeṣina ti fi ẹsun kan ijọba ipinlẹ Ọyọ pe o ti n ti ọwọ bọ ilana ati jẹ Alaafin tuntun nilu Ọyọ.

Ọmọọba naa pe awọn eeyan kan to n ṣoju ijọba ni wọn n toju bọ ilana naa ti wọn si n sọ pe iṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ l’awọn n jẹ.

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, @Alaafin

Ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun 2022 ni Alaafin Ọlayiwola Adeyẹmi kẹta waja, eyi ti o si ti ṣi alafo ori itẹ pataki ilẹ Yoruba naa silẹ fun saa tuntun.

Lati igba naa wa bayii ni awọn afọbajẹ lode Ọyọ ti bẹrẹ igbesẹ wiwa ọmọ oye.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹjọ ọdun 2022, lo ti sọrọ.

Ọmọọba Adeṣina ni lootọ awọn olori awọn Ọmọọba ti wọn n pe ni Baba Iyaji ati awọn Oyọ mesi bẹrẹ eto naa lai figba kan bọkan ninu, ṣugbọn nigba to ya lawọn agbefọba kan bẹrẹ si ni yọjuran sii.

“Alaga ijọba ibilẹ Atiba kọ ninu lẹta kan lọjọ kẹsan an, oṣu kẹjọ, ọdun 2022 pe ijọba ipinlẹ Ọyọ, nipasẹ ileeṣẹ ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, dari oun lati bẹrẹ ilana yiyan Alaafin tuntun lati idile oye Agunloye.

“Leyi ti wọn fi n yọ awọn idile oye mẹsan an to ku ti ijọba ti da mọ lati ọjọ kẹjọ an oṣu kejila ọdun 1976, ti iwe alakalẹ ofin Gazette ọdun 1995 si ti la kalẹ silẹ.”

O ni awọn aṣẹ ti Alaga ijọba ibilẹ Atiba n pa yii tako ileri ti gomina ipinlẹ Ọyọ Seyi Makinde ṣe pe oun tabi ijọba oun ko ni toju bọ ilana yiyan Alaafin tuntun fun ilu Ọyọ.

Ilana ofin oye to de oye Alaafin jijẹ nijọba ipinlẹ Ọyọ yoo tẹle – Seyi Makinde

Gomina Seyi Makinde ti kọkọ sọrọ nipa re.

Lasiko eto isinku ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe fun Alaafin Adeyẹmi loṣu kẹfa ọdun 2022, gomina ipinlẹ Ọyọ lo sọrọ.

O ṣe e lalaye nibi ayẹyẹ naa pe lootọ lawọn kan ti wa n ba oun pe ki oun gbe igbesẹ yii tabi tọhun lori yiyan Alaafin tuntun,

ṣugbọn oun ti ṣalaye fun won pe lẹyin ohun gbogbo to ti wa ninu ofin ilana oye jijẹ fun Alaafin ti ilu Ọyọ, oun tabi ijọba oun ko ṣetan lati da si.

Bakan naa ni amugbalẹgbẹ fun gomina Makinde lori ọrọ aṣa ati irinajo afẹ, Kazeem Ademọla ṣalaye nibi ajọdun Sango to waye lọjọ diẹ sẹyin pe gomina Makinde ko tii yẹsẹ kuro lori ipinnu rẹ fun awọn eeyan ilu Ọyọ lori yiyan alaafin tuntun.

Ta ni Alaafin to waja?

Alaafin Adeyẹmi kẹta ni Alaafin kẹta ti yoo jẹ lati idile.