Èèyàn mẹ́jọ farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ondo

Ondo accident

Eeyan bii marundinlogun lori ko yọ ni Oke-Odo, lopopona Owo si Akurẹ ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye nibẹ.

Ijamba ọun to waye nigba ti ọkọ akero bọọsi kan pẹlu nọmba KPA 248 XA (Kogi) ati ọkọ Honda kan pẹlu nọmba LND 132 FY Lagos fori sọra wọn lọna naa, leyii to fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ fun ọpọ igba.

Ondo accident
Ondo accident

Asojukọroyin BBC News Yoruba ti ijamba naa ṣoju rẹ jabọ pe awọn ọmọ ologun lo gbiyanju lati doola ẹmi awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa ki awọn ẹṣọ alaabo oju popo to de.

Ondo accident

Ohun to ṣẹlẹ si awakọ bọọsi ọun ni ko ye ni ni pato leyii to mu ko lọ kọlu ọkọ Honda lọna tirẹ to si mu ki ọkọ mejeeji bajẹ kọja ala.

Ondo accident
Ondo accident

Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni ti ẹmi rẹ sọnu ninu ijamba naa, awọn bii mẹjọ lo farapa ti awakọ ọkọ Honda naa ko si le da duro funra rẹ ki wọn to ko wọn lọ ile iwosan.