Ìpínlẹ̀ Osun pé ọdún 31, Oyetola, Adeleke tún tako ara wọ́n lórí ipò tí ìpínlẹ̀ náà wà

Bi ipinlẹ Ọṣun ṣe n ṣe ajọyọ ayajọ ọdun kọkanlelọgbọn ti wọn da a silẹ, gomina to wa nipo bayii ni ipinlẹ naa, Gboyega Oyetọla pẹlu ẹni ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo gomina nibẹ, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ki awọn eeyan ipinlẹ naa ku oriire.
Ninu ọrọ ti awọn mejeeji gbe jade, wọn tako ara wọn lori ipo ti ipinlẹ naa wa bayii.
Bi Oyetọla ṣe n fọnrere pe oun ti ṣe iwọn ti oun le ṣe oun ko si ja araalu ni tan mọọ, ni Adeleke n lọgun pe ipo tipinlẹ naa wa ko jọju, ṣugbọn oun ṣetan lati mu igba ọtun bọ wa.
Ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2022 lo pe ọdun mọkanlelọgbọn ti wọn da ipinlẹ Ọṣun silẹ.
Ni dede ọjọ yii ni ọdun 1991 ni ijọba ologun nigba naa labẹ akoso ọgagun Ibrahim Babangida ṣe idasilẹ ipinlẹ Ọṣun, Anambra, Delta, Edo, Jigawa, Kebbi, Kogi, Enugu ati Taraba.
Iṣejọba mi ko ja ẹnikẹni kulẹ - Oyetọla

Oríṣun àwòrán, Gboyega oyetọla/twitter
Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin, Ismail Omipidan fi sita, gomina ipinlẹ Ọṣun Gboyega Oyetọla ṣalaye pe awọn ohun to ṣe koko fun araalu ni ijọba oun gbe eto rẹ le lori eyi to ni ajọ idagbasoke okeere nilẹ Amẹrika, DFID ti jẹri si pẹlu ninu abajade agbeyẹwo ipinlẹ si ipinlẹ to ṣe.
“A ṣeleri sisan owo oṣu, a ko si yẹ adehun yii. A ṣeleri lati san owo awọn oṣiṣẹfẹyinti, a ko yẹ eyi a ṣeleri lati kọ afara Ọlaiya, a si ti ṣe eyi.”
Gomina Oyetọla fi kun un pe iṣejọba oun ṣi n ba iṣẹ lọ lori ṣiṣeto ọrọ aje ti ko rọgbọku le orisun kan ṣoṣo.
Mo maa da iṣejọba rere pada si Ọṣun – Sẹnetọ Adeleke

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke/ twitter
Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ṣalaye ninu atẹjade kan to fọwọsi pe oun yoo da eto iṣejọba to mu igbayegbadun araalu, ijihin iṣẹ faraalu lọkunkundun pada si ipinlẹ naa.
Adeleke kan sara sawọn babanla ipinlẹ naa atawọn gomina to ti jẹ ṣaaju ; o ni ilakaka wọn lo mu ipinlẹ Ọṣun de ibi to de lọwọ bayii.
“Mo fẹ sọ ọ laifọtape wi pealaa rere ti awọn babanla wa ni fun idasilẹ ipinlẹ yii ko tii wa si imuṣẹ. Awọn ohun elo amayedẹrun wa ko si ni ipo amuyangan. Ipo kẹrindinlogoji ni ipinlẹ Ọṣun wa ni idanwo aṣekagba WAEC laarin ipinlẹ mẹrindinlogoji ati ilu Abuja. Awọn ọdọ ko ni iṣẹ lọwọ. Eto abo to mẹjẹ ti di wahala ojojumọ. Gbese kun ọrun ipinlẹ wa babi. A gbọdọ yi eyi pada.”












