Ìgbìmọ̀ afọbajẹ ìlú Oyo já 61 dànù lára àwọn tó ń dupò Aláàfin

Oríṣun àwòrán, Other
Àwọn afọbajẹ ilu Oyo, ti sayẹwo fun oludije mejidinlọgọta to fẹ dupo Alaafin.
Saaju ni igbimọ naa kéde pe ọmọ oye mọkandinlọgọfa lo fi ifẹ hàn lati di Alaafin tuntun.
Osu kẹrin ni Ọba Adeyemi papoda lẹni ọdun mẹtalelọgọrin, lẹyin to lo ọdún mejilelaadọta lori oye.
Iwe iroyin abẹle, Daily Post jabọ pe lọjọ Ẹti to kọja, ni awọn afọbajẹ buwọlu mejidinlọgọta lara àwọn ọmọ ọba, ti wọn si já mọkanlelọgọta lẹyin ayẹwo.
Iroyin sọ pe awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Oyo wa nibi ti àwọn ọmọ igbimọ afọbajẹ ti ṣe ayẹwo fun awọn oludije naa.
Lẹyin ti igbimọ ba pari isẹ wọn, ní wọn yoo fi orúkọ ẹni to ba tọ si ranṣẹ si ijọba.
Lara awọn to lẹtọ si ipo Oba naa ni Biṣọọbu agba ijọ Eleto ti Methodist ni, Biṣọọbu agba Ayo Ladigbolu.
Biṣọọbu naa lo tile ni ẹni ọdun mẹrinlelogọrin bayii.
Awọn orukọ ọmọ oye ti aye n pariwo naa niyii:
OKE APO (GBADEGESIN):
1.Abdul Rashidi Adewale GBADEGESIN
2.Omowe Abidoye GBADEGESIN
3.Abdrasak Adegoke GBADEGESIN
4.Kabiru Adebayo GBADEGESIN
5.Isiak Olatunde GBADEGESIN
6.Basiru Adeniyi GBADEGESIN
7.Monjeed GBADEGESIN
8.Lukman Adelodun GBADEGESIN
9.Babajide Aderoju GBADEGESIN
10.Abdmonjeed Adekunle GBADEGESIN
ILAKA OLAWUWO:
11.Ajibade Adebayo ADELADAN
12.Tella Biliaminu KOLAWOLE
13.Tiani Hammed ADEBAYO
14.Salami Saheed BABATUNDE
15.Ladigbolu Adewale ADEREMI
16.Adekunle Mutahir ADEGBOYE
17.Alh. Tesleem Oriade LADIGBOLU
18.Adekunle Kamal ADEYEMI
19.Adebisi Jeleel ADENIYI
ISALE-OJA:
20.Oluokun Kasali AGUNLOYE
21.Adekunle Gafar ADEBAYO
22.Tella Meroof ADENIYI
23.Owoade Wahab Folorunso ADEREMI
24.Adewusi Mukaila OLANREWAJU
25.Olaide Dauda OLADIMEJI
26.Tella Adeniyi KAREEM
27.Agunloye Adelayo ADEREMI
28.Aderogba Idowu AGUNLOYE
29.Morounranti Hakeem ALAYOAYO
30.Gbadegesin Taofeek AGUNLOYE
31.Remilekun Enitan ADENIYA
32.Razak ALAYOAYO
33.Akinade Abdul Rahman ALAYOAYO
LADIGBOLU:
34. Biṣọọbu Agba Omọọba Lawrence Sanda Ayo LADIGBOLU
35.Lukman Alabi Olugbenga LADIGBOLU
36.Hakeem Abiodun Adeyanju Ayinde LADIGBOLU
37.Ayobami Adewumi Sanda LADIGBOLU
38.Amidu Abiodun LADIGBOLU
39.Muideen Adekunle LADIGBOLU
40.Kolade Tunde Saani LADIGBOLU
41.Adegboyega Ibrahim LADIGBOLU
42.Abdulquadri Opeyemi LADIGBOLU
43.Ismaila Aderemi Belawu Adekunle LADIGBOLU
44.Adebimpe Wasiu Abiodun LADIGBOLU
45.Taofeek Adewumi LADIGBOLU
46.Rasaki Kamorudeen Osuolale LADIGBOLU
OWOADE AGURE:
47.Hakeem Babatunde Adetunji OWOADE
48.Ibrahim Abiodun Olayiwola OWOADE
BBC ko tii le fidi àwọn ti igbimọ afọbajẹ buwọlu, tabi awọn ti wọn já kuro.
sugbọn nkan to daju ni pe ẹnikan ninu awọn tì wọn buwọlu ni wọn yoo pada yan gẹgẹ bii Alaafin Oyo tuntun ti yoo maa ṣakoso Oyo.














