Ìdí rèé tí mo fi gba agbẹjọ́rò 48 láti kojú Oyetola nílé ẹjọ́ - Adeleke

Oríṣun àwòrán, Other
Gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti gba agbẹjọro ti ko din ni mejidinlaadọta, lati ṣoju rẹ niwaju igbimọ to n gbọ awọn ẹsun to ṣuyọ lẹyin idibo.
Gomina lọwọlọwọ, Gboyega Oyetola, lo pe ẹjọ siwaju igbimọ naa nitori esi idibo gomina to waye ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ko tẹẹ lọrun.
Agbẹnusọ fun igbimọ oluṣakoso eto iponlongo fun Sẹnetọ Adeleke, Ọgbẹni Kolapo Alimi, sọ fun BBC pe awọn gba iye agbẹjọro to pọ bẹẹ nitori pe ọna mẹta ni ẹjọ ti Oyetola pe.
O ni ajọ INEC ni olujẹjọ akọkọ, ẹgbẹ PDP jẹ ikeji, gomina tuntun, Ademola Adeleke si jẹ olujẹjọ kẹta.
‘Agbẹjọro mẹẹdogun la gba fun isọri kọọkan ẹjọ̀ onigun mẹta ti Oyetola pe’
Ọgbẹni Alimi sọ pe nitori naa ni awọn ṣe gba awọn agbẹjọro to pọ, ninu eyi ti agba agbẹjọro mẹjọ (Senior Advocate of Nigeria, SAN), wa fun amojuto to peye.
“Ninu iru ipẹjọ bayii, a mọ pe iṣẹ yoo pọ, to fi mọ oriṣiriṣi ẹri ati awọn iwe akọsilẹ.
Diẹ lara awọn agbẹjọro naa yoo ma a mojuto igbẹjọ kọọkan, awọn miran yoo mojuto ọrọ awọn ẹlẹri, ti awọn kan yoo si mojuto igbẹjọ gan-an-gan.
Alimi sọ pe bi ẹni pe agbẹjọro mẹẹdogun ni awọn gba fun igbẹjọ kọọkan, ti apapọ wọn si jẹ mejidinlaadọta.
Ṣaaju ni ẹgbẹ PDP sọ niwaju igbimọ eto idibo naa pe ko da ẹjọ ti Gomina Oyetola pe nù, nitori pe ni gbogbo ọna ni oludije PDP, Adeleke, fi bori ninu idibo naa.
Akojọpọ ibo 403, 271 ni Ademola Adeleke ni, ti Gomina Oyetola si ni 375,027.












