Ṣé lóòtọ́ọ́ ní ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún Ademola Adeleke jẹ́wọ́ pé òun pa èèyàn kan ní Ede?

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, @ademolaadeleke

Iroyin kan ti n ja rain lori ayelujara pe ẹsọ alaabo gomina tilu dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti jẹwọ ẹsun ipaniyan.

Afurasí naa, CSP Omoyele Adekunle ni iroyin naa salaye pe o jẹwọ pe oun ni oun pa ọkan lara awọn eeyan ti wọn pa laipẹ yii nilu Ede.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni BBC Yoruba mu iroyin kan wa fun yin pe eeyan meji, Abideen ati Kafayat Olalekan, ti oun loyun sinu ni tiẹ ku.

Awọn eeyan naa, ti wọn wa lati idile kan soso, si la gbọ pe wọn yinbọn pa tori aawọ oselu to waye nilu Ede, eyi to kan asofin to n soju ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin ipinlẹ Osun.

Se lootọ ni ẹsọ alaabo Ademola Adeleke lọwọ ninu iwa ipaniyan naa?

Gẹgẹ bi iroyin lawọn oju opo ayelujara naa ti wi, lasiko ti ẹka ọtẹlẹmuyẹ ti ileesẹ ọlpaa ko sodi, n se iwadi ipaniyan naa ni Omoyele jẹwọ bẹẹ.

Wọn ni afurasi akọkọ lori isẹlẹ yii ni Omoyele, ti wọn si fi ọrọ wa lẹnu wo lori isẹlẹ naa nitori oun lo lewaju ikọ alaabo ti wọn lo pa awọn eeyan naa.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa si ni iroyin naa ni Omoyele ti jẹwọ pe lootọ ni oun pa eeyan kan laarin awọn eeyan meji to ku lasiko rogbodiyan naa.

Ki ni ileesẹ ọlọpaa Abuja sọ nipa isẹlẹ naa?

Ọna lati fi idi otitọ mulẹ nipa iroyin to n ja rainrain nilẹ naa lo mu ki BBC Yoruba kan si ileesẹ ọlọpaa nilu Abuja, lati wadii ohun gbogbo daju.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa pata nilẹ wa, Olumuyiwa Adejobi, ni irọ to jinna sootọ ni iroyin naa.

Adejobi ni abọ iwadii ileesẹ ọlọpaa apapọ lori isẹlẹ naa ni wọn ti fi sọwọ si ọgba agba ọlọpaa pata, ko si tii lu sita.

O wa koro oju si bi awọn eeyan se n gbe ahesọ ọrọ kiri nipa abọ iwadii naa, eyi ti ko tii han si araye.

Ile ti wọn jo lasiko ija oselu ni Ede

Ki lo ti waye sẹyin lori laasigbo oselu ni Ede?

Bẹẹ ba gbagbe, BBC Yoruba ti mu iroyin wa fun yin nipa laasigbo oselu to waye ni bii osu kan sẹyin nilu Ede.

Isẹlẹ naa lo waye lẹyin ti oludije gomina fun gb oselu PDP, Ademola Adeleke jawe olubori ninu eto idibo naa.

Wahala naa lo su yọ nitori aawọ owo pinpin to bẹ sil laarin awọn ọdọ ninu ẹgbẹ oselu PDP ati olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin ipinlẹ naa, Asofin Kofoworola.

Awọn ọdọ naa lo fi ẹsun kan asofin Kofoworola pe ko fi owo ti wọn fi ran si awọn jisẹ, ti laasigbo si bẹ silẹ, eyi to mu ki awọn ọlọpaa wa da si ọrọ naa.

Lẹyin o rẹyin, ẹmi eeyan meji ti bọ sinu laasigbo naa, orukọ wọn si ni Abideen Olalekan ati Kafayat Olalekan, ti wọn wa latinu ẹbi kan soso.

Bakan naa ni aawọ yii fọnna soju debi pe wọn sun ile Alhaja Silifatu Olalekan, tii se iya Abideen ati iya ọkọ Kafayat.

Laasigbo naa lo tun mu ki wọn tun sun ile awọn obi asofin Kofoworola, ti wọn ko si tun mọ ibi ti baba asofin naa wa.