N kò fi Peter Obi ṣe ààyò olùdíje ààrẹ, máà kéde èròǹgbà mi fún Nàíjíríà láìpẹ́ – Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @PeterObi
Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Olusegun Obasanjo ti sọ pe oun ko ni aayo lara awọn oloṣelu to n dije du ipo Aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023.
Obasanjo lo sọ ọrọ naa niluu Mina, nipinlẹ Niger lasiko to lọ ṣabẹwo si adari Naijiria tẹlẹ, ọgagun Abdulsalam Abubakar.
Baba Iyabo ṣalaye pe tako igbagbọ ọpọ eeyan pe oun n satilẹyin fun Peter Obi, tii se oludije aarẹ fun ẹgbẹ iselu Labour, o ni oun ko ni aayo lara oludije bi ko ṣe bi Naijiria yoo ṣe dara.
O ni “Mi o ni aayo kankan lara awọn to n dijdu ipo Aarẹ, ohun to jẹ mi logun ni ilọsiwaju Naijiria.”
Ohun to gbe Obasanjo lọ si Minna
Aarẹ Naijiria nigba kan ri naa ni ohun to gbe oun lọ si Minna ko ṣẹ̀yìn àárẹ̀ to n ṣe Abdulsalami Abubakar.
O sọ pe “Mo wa sibi lati ṣe abẹwo si ọrẹ mi to n ṣaisan ranpẹ, lootọ ni mo ti kọkọ fẹ bẹ ẹ wo niluu London, amọ ọjọ gan ti mo de London ni oun naa pada si Naijiria.”
“Idi ree ti mo fi pinnu lati wa si ile rẹ, o tobi lọwọ mi, lo jẹ ki n wa sibi.”
“Ti mo ba ri ẹni ti ara rẹ ko da, mo maa ṣabẹwo sọdọ rẹ nitori ara mi ṣi mokun daadaa.”
Nnkan bii aago mejila abọ ọsan ni Obasanjo balẹ si ile Abubakar, wọn ṣe ipade idakọnkọ, lẹyin naa lo fi ibẹ silẹ ni nnkan bii aago kan kọja iṣeju diẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Obasajo ṣe ipade pẹlu oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, to fi mọ gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, niluu London.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Okezie Ikpeazu to jẹ gomina ipinlẹ Abia, gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ati gomina ipinlẹ Cross River tẹlẹ, Donald Duke, atawọn eeyan mii.
Ipade ọhun ni ọpọ eeyan gbagbo pe ko ṣẹyin eto idibo gbogbogbo ọdun to n bọ.












