Olórí tẹ́lẹ̀ ní Soviet Union, Mikhail Gorbachev, yóò wọ káà ilẹ̀ sùn lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mikhail Gorbachev, olori to kẹyin fun Soviet Union, ẹni to mu opin de ba ọpọlọpọ ogun ni wọn yoo gbe wọ kaalẹ lẹyin to jade laye lẹni odun mọkanlelaadọrun-un.
Aarẹ Orilẹede Russia, Vladimir Putin, ni ko ni anfani lati darapọ mọ isinku naa nitori pe oni ọpọlọpọ isẹ wa niwaju rẹ.
Gorbachev, ẹni to di olori Soviet Union lọdun 1985 ki ipinya to de saarin wọn kopa ribiribi nínu idagbasoke orilẹ ede naa, tosi tun ṣe afihan ajọ naa si agbaye.
Labẹ akoso Gorbachev ni Soviet Union kuta lọdun 1991, ti ọpọlọpọ si igbagbọ pe oloogbe naa kopa ninu bi orilẹ ede naa ṣe tuka.
Yatọ si Orilẹede Russia, Gorbachev jẹ ẹni tí ọpọlọpọ orilẹ ede lagbaye ni ibọwọ fun nitori ipa to ko ninu itan.
Gorbachev ni wọn yoo sin ile oku to tobi julọ lorilẹ ede Russia níbi tí pupọ lara awọn eekan lorilẹede Russia wọlẹ sì.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ Iyawo rẹ Raisa Gorbachev, ẹni to jade lọdun 1999 lẹyin to lugbadi aarun 'Leukaemia' ni wọn olori orilẹ ede tẹlẹ ri naa yoo sun si.
Awọn aarẹ kaakiri Orilẹ ede Agbaye ti ransẹ ibanikedun si awọn mọlẹbi Gorbachev, tí wọn si sapejuwe rẹ gẹgẹ olori to kopa ribiribi sì idagbasoke lagbaye.
Aarẹ Orilẹede Amẹrika, Joe Biden ni igbesi aye Gorbachev jẹ awokọse fun ọpọlọpọ awọn olori lagbaye.
Bákan naa, nigba ti o ransẹ ibanikedun, Aarẹ Orilẹ ede Russia, Vladimir Putin naa ba awọn mọlẹbi kẹdun lori iku akọni ọkùnrin.















