Fake News: Ayédèrú Dino fẹ́ fún èèyàn mẹ́wàá ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà tí Atiku bá wọlé

Oríṣun àwòrán, Instagram/dinomelaye
Ibeere ''ki lo yẹ ki a fi ṣajọyọ ti Atiku ba pegede ninu ibo Aarẹ?'' ni Sẹnẹto Melaye @dinomelaye14 kọkọ fi bẹrẹ loju opo Twitter.
Kato wi ka to fọ ọ, o ti ṣe'pinu pe ohun yoo fun eeyan mẹwa ni miliọnu Naira kọọkan ti @atiku ba wole gẹgẹ bi Aarẹ orileede Naijiria!
Milọnu mẹwa lasiko ọgbẹlẹ yii?
Ere abi awada? kia lawa na bẹrẹ iwaadi ti a si pada wa ri i wi pe kii ṣe Dino Melaye gangan lo fi ikede yi sita.
Ayederu ni orukọ Twitter naa jẹ nitori pe @dino_melaye lorukọ ojulowo Senetọ Dino Melaye loju opo Twitter.
Bi o ba ti n bawọn pin ọrọ yii, iwọ naa ti dara pọ mọ awọn ti BBC ati ọpọ awọn amoye lawujo ni wọn n dakun wahala iroyin ẹlẹjẹ to gbode.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Sẹneto Dino Melaye to n soju awọn eeyan iwọ oorun ipinlẹ Kogi ni gbungbun orileede Naijiria kii ṣe aimọ lagbo oṣelu Naijiria.
Bi ko ba maa ba awọn ọlọpaa woya ija, oun ati Gomina ipinlẹ rẹ ko ni ma salai ni aawọ.
Lẹnu ọjọ mẹta yii ti idibo Aarẹ sunmọ, awọn ọmọ Naijiria ko fi bẹẹ gbohun rẹ amọ ni bayii ti ayederu ''Dino Melaye'' ti fi ikede miliọnu mẹwaa Naira sita, awọn eeyan ti n fun un lesi loju opo Twitter.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3
Ohun to ṣeni laanu ni wi pe Sẹnẹtọ Dino Melaye to jẹ ojulowo gangan kọ ni ka awọn esi yi .
Bi a ti ṣe n sọrọ yi, Sẹnetọ Dino Melaye ko tii fesi pada si ọrọ pe o fẹ pin miliọnu mẹwa Naira fun awọn eeyan.
O ṣeeṣe ki o jẹ wahala idibo ile asofin agba to n kopa ninu rẹ eleyi ti Inec sun siwaju lo n ba po o.
Amọ ṣa loju opo Twitter rẹ, ọrọ to nii ṣe pẹlu iwọde ti awọn obinrin Ebira kan ṣe lati fi ẹhonu han si ijọba ''ọta rẹ'' Gomina Yahaya Bello ni o fi sita.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4