FIFA U-20 World Cup: Senegal sin Nàìjíríà lọ'lé pẹ̀lù ìgbájú ìgbámú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajẹtun iya ni ẹgbẹ agbabọọlu Flying Eagles ti Naijiria jẹ lọwọ Senegal ninu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA U-20 to n lọ lọwọ lorilẹ-ede Poland.
Senegal lu Naijiria bi aṣọ ofi pẹlu ami ayo mẹta sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele ẹlẹni mẹrindinlogun(Round of 16).
Amadou Sagna lo ṣide iya fun ikọ Flying Eagles lẹyin to gba goolu akọkọ sawọn fun Senegal ni iṣẹju mẹrindinlogoji.
- Ibanuje d'orí agbà k'odò, Ruiz fi ẹ̀ṣẹ́ sọ Anthony Joshua di ọmọ ológo àná
- Liverpool da ata gúngún sójú Tottenham gba ife ẹ̀yẹ Champions League
- Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lágbo eré bọ́ọ̀lù, Reyes to gbá bọ̀ọ́lù fún Arsenal rí jáde láyé
- Donald Trump ti pàdé Ọbabìnrin Elisabeth tilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì
- Ilé wó pa Jide, ọmọ ọdún mọ́kànlá, l'Oṣogbo
Ibrahima Niane fọba le fun Senegal ni iṣẹju to kẹyin ni ipele akọkọ ere bọọlu naa, lo ba bi ami ayo meji sodo.
Naijiria gbiyanju agbara wọn ṣugbọn aṣọ ko ba Ọmọyẹ mọ, Ọmọyẹ ti rin hoho wọja, ami ayo kan ṣoṣo ni wọn le da pada.
Ẹ o ranti pe Senegal fiya jẹ Naijiria pẹlu ami ayo meji sodo ninu idije WAFU lọdun 2018 naa.
Ikọ Senegal yoo koju ẹni to ba jawe olubori ninu ẹgbẹ agbabọọlu Japan tabi South Korea ni ipele kọmẹsẹọyọ ẹlẹni mẹjọ.
Nàìjíríà yóò dá ṣèríà fún Senegal lónìí- Balógun Flying Eagles
Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Flying Eagles Naijiria, Ikouwem Utin sọ pe oun ati awọn akẹgbẹ rẹ ti ṣetan lati gbẹyẹ lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Sẹnegal.
O ni inu ifẹsẹwọnsẹ ipele ẹlẹni mẹrindinlogun ọjọ Aje, ninu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA U-20 lorilẹ-ede Poland ni yoo ti ṣẹlẹ.
Bo tilẹ jẹ wi pe Senegal fiya jẹ Naijiria pẹlu ami ayo meji sodo ninu idije WAFU lọdun 2018, Utin ni didun lọsan yoo so fun ikọ Flying Eagles nigba ti wọn ba koju Senegal lonii.

Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF
Balogun Flying Eagles ni awọn yoo lo iriri tawọn ti ni fi ṣẹgun Senegal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ọmi ayo kọọkan ni Naijiria ta pẹlu Ukraine ninu ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ti wọn gba ni isọri wọn lati pegede fun ipele ẹlẹni mẹrindinlogun.
Naijiria lu orilẹ-ede Qatar ni alubami ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba ninu idije FIFA U-20, ṣugbọn wọn fidi rẹmi ninu ere bọọlu keji lẹyin ti ikọ agbabọọlu Amẹrika la wọn mọ lẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria ti sọrọ pẹlu igboya pe Flying Eagles yoo jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Senegal.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Naijiria ko tii gba ife ẹyẹ agbaye FIFA U-20 ri, ṣugbọn wọn ti wọ ipele aṣekagba idije naa lẹẹmeji ọtọtọ.













