Osogbo Building collapse: Ògiri ilé wó pa Jide ọmọ ọdún mọ́kànlá l'Oṣogbo

Oríṣun àwòrán, citymirrornews.com
Ọfọ nla lo ṣẹ lagbegbe Kajọla ni ilu Oṣogbo lọjọ Aiku nigba ti ile alamọ kan da wo ti o si pa ọmọ ọdun mọkanla kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Jide.
Ile ọlọjọ pipẹ naa to wa ni agboole Kegbe ni agbegbe Kajọla ni ilu Oṣogbo da wo lu Jide lasiko to fi n gba ẹgbẹ ile naa kọja lọ ni tirẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣalaye pe awọn aladugbo gbe e lọ si ileewosan kan ni agbegbe Oke-Baalẹ ṣugbọn ti awọn oṣiṣẹ ileewosan naa ni ọrọ rẹ kọja agbara awọn.
Awọn aladugbo tun dari rẹ lọ si ileewosan nla ti LAUTECH, ṣugbọn Jide jade laye ki wọn to gbe e de'bẹ.
Ọkan lara awọn olugbe ile naa to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe "inu ile mi ni mo wa ti mo si ṣa dede gbọ iro nla kan, mo jade lati wo ohun to ṣẹlẹ ni mo ba rii pe apa kan ile ti mo n gbe ti wo lulẹ. Ogiri ile naa wo lu ọmọdekunrin kan to n kọja lọ, o si ku."
Ko tii si ẹni lee sọ ohun to fa ijamba ile to wo naa titi di igba ti a fi ko iroyin yii jọ.









