Genotype test: Ilé aṣòfin kàn án nípá fáwọn tó fẹ́ ṣèyàwó láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀

Dandan lowo ori; tulaasi laṣọ ibora.
Ni bayii, o ti di didan fawọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin ti wọn ba fẹ ṣegbeyawo lati ṣe ayẹwo ẹjẹ ki wọn to lọ sori pẹpẹ.
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin Naijiria lo kan an nipa fawọn obinrin atawọn ọkunrin to ba fẹ fẹ ara wọn ni Naijiria ninu apero wọn l'Ọjọbọ.
Awọn aṣofin ti wa kepe awọn ẹka ijọba to n ṣe eto igbeyawo, awọn ṣọọṣi atawọn mọṣalaaṣi wi pe ki wọn maa beere esi iyẹjẹwo ki wọn to so ẹnikẹni pọ.
- Àìsàn ìtọ̀ súgà kò túmọ̀ sí pé èèyàn ti gba ọjọ́ ikú- Dókítà Wilson
- Mo bọ́ lọ́wọ́ igbó mímu ṣùgbọ́n ìnira ilé Aafa Ọlọrẹ ti pọ̀jù- ọ̀dọ́ kan
- Wo ìlú tí wọ́n tí ń ta ọmọ ọ̀dọ̀ kan fún #1.3M lórí ayélujára
- Mo bọ́ lọ́wọ́ igbó mímu ṣùgbọ́n ìnira ilé Aafa Ọlọrẹ ti pọ̀jù- ọ̀dọ́ kan
- Ọlọ́pàá kan jáde láyé, èèyàn méjì fara gbọta lásìkò ìdigunjalè ní Falomo l‘Eko
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin ni igbesẹ yii ṣe pataki lati dena aarun arunmọleegun ni Naijiria.
Gbogbo ile lo tẹwọgba aba naa ti aṣofin Umar Sarki to gbe e wa pe akori rẹ ni ''Kepe ile iṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilera lati wa ọna ati dẹkun aarun arunmọleegun ni Naijiria.''
Awọn aṣofin tun kepe ẹka ijọba to n ri si eto ilera lati pese iwosan ọfẹ fawọn to laarun arunmọleegun.
Ni afikun, wọn rọ ijọba lati sọ fawọn ile ijọsin ati ẹka idajọ lati maa lo esi ayẹwo ẹjẹ gẹgẹ ọkan lara amuyẹ fun igbeyawo.
Ile igbimọ aṣoju-ṣofiun tun rọ ijọba lati fi idanilẹkọọ lori aarun arunmọleegun sinu eto ẹkọ ile iwe alakọbẹrẹ ati ti girama ni Naijiria.
Ile paa laṣẹ fun igbimọ to n ri si eto ilera, iroyin, ọrọ ilanilọyẹ ati ọrọ lati rii pe igbesẹ yii di imuṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, aṣofin to gbe aba naa silẹ, Ọgbẹni Sarki ni iwadii fihan pe aarun arunmọleegun ti wa nilẹ Afirika fun bi ẹgbẹrun un mejila ọdun, eleyi ti ilẹ Adulawọ ko si tii ṣe nnkan gbogi lati dẹkun rẹ.
Iwadii fihan pe Naijiria lawọn to larun arunmọleegun ti pọju lagbaaye pẹlu miliọnu mẹta aabọ eeyan o le diẹ to larun naa.
Bakan naa ni iwadii fihan pe aadọjọ ọmọ ikoko ninu ọọdunrun tawọn eeyan n bi lagbayee lọdọọdun lo wa lati Naijiria.















